Posts

Showing posts from September, 2026

Ẹyin ara agbegbe aarin gbungbun Ogun, Ogun Central akoko to lati fibo yin Ọmọluabi Pọnbele,Oluwafẹmi Abiọdun-Oni wọle.

Image
Bi o ti ku fẹrẹ ki eto ibo waye jakejado orileede yii tawọn oludije si ti n jade lati du awọn ipo kọọkan. Bẹẹ ni ipolongo si ti bẹrẹ yatọ sipo Gomina atawọn aṣofin ipinlẹ. Ki i ṣe tuntun mọ pe ọkan lara awọn oludije fun aṣofin agba fun ẹkun aarin gbungbun iyẹn Ogun Central ni Onimọ ẹrọ Samuel Oluwafẹmi Abiọdun Oni, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, ẹni ti Ọlọrun sọ pe akoko ti to fun un lati wa sin eeyan rẹ. Ohun to daju ni pe latigba ti ajọ eleto idibo iyẹn INEC ti fi ontẹ lu agba oṣelu naa gẹgẹ bi oludije, lawọn araalu naa ti n fi atilẹyin wọn han si, ti wọn si lawọn nigbẹkẹle ninu ẹ lati jẹ aṣoju wọn niluu Abuja. Ko le ṣe ko ma ribẹ, nitori ẹni ti wọn ba ti pe ni ọmọluabi, ko si ki wọn maa ri awọn iwa alubarika yii lara ẹ. Awọn to mọ oludije ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC yii sọ pe ki i ṣe akoko to fẹẹ gbegba oṣelu lo ṣẹṣẹ di ọmọluabi, wọn ni ọmọ ba ọla nile, to tun fawọn jẹ ninu ọla ẹ ni. Ọpọ awọn ipa pataki ti wọn lo ti ko lo ti ni ẹmi sisin awọn eeyan ẹ ṣọkan, ti ko si fọrọ wọn ṣere, aṣiwaju ati adari re...

Bi Oluwafẹmi Abiọdun-Oni oludije sẹnetọ fun ẹkun Ogun Central labẹ ADC dẹru jẹjẹ, wọn ko mọ ọna ti yoo gba yọ si wọn.

Image
Bi ere ni wọn kọ n pe tẹlẹ nigba ti wọn gbọ pe gbaju gbaja onimọ ẹrọ nni, Samuel Oluwafẹmi Abiọdun-Oni, ni ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, ipinlẹ Ogun, lo lati dije fun ipo aṣofin agba fun ẹkun Ogun Central, ọpọ ko gbagbọ,  ṣugbọn nigba ti ariwo ọkunrin naa ti n lọ lọtun, to n lọ si osi, ọrọ naa si ti di ẹru jẹjẹ mọ wọn lọwọ. Gẹgẹ bi a ṣe mọ, tẹlẹtẹlẹ ariwo APC ati PDP lawọn araalu n gbọ tẹlẹ fun ibo ti yoo waye amọ bayii okiki ẹgbẹ oṣelu ADC naa ti nnkan paapaa ni aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, ohun to si faa ni bi oludije wọn ko ṣe fọrọ ibo naa ṣere, to si n sọ pẹlu ifọkanbalẹ pe oun loun yoo jawe olubori. Ko le ma ri bẹ, nitori ọrọ agba kan to sọ pe ọmọ akin kan ko gbọdọ ṣojo, idi niyii to fi jẹ pe gbogbo nnkan to wa lọkan Abiọdun Oni lakooko yii ni bi yoo ṣe jawe olubori. Bi a ba si ni ka sọ tododo, oludije aṣofin agba yii to wa lati ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipnlẹ Ogun ki i ṣe ọmọde nidii oṣelu, agba ọjẹ to ti fawọn iriri to di awọn ipo mu ni. Bẹẹ lo ṣe jẹ pe ko si...