Posts

LYMP kí Ṣẹgun Ṣówùnmí kú oríire ìyànsípò rẹ̀ sínú ìgbìmọ̀ ìpolongo ààrẹ

Image
  Ẹgbẹ awọn oniroyin ni ede abinibi, League of Yoruba Media Practitioners (LYMP), ti ki gbajumọ oloṣelu ati olori pataki nilu Ẹgba, Ọdọfin Ṣẹgun Ṣowunmi, ku oriire lori iyansipo rẹ sinu igbimọ ipolongo aarẹ ti ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) ṣe atunṣe rẹ. Ṣowunmi wa lara awọn eekan igbimọ naa to ma mojuto ẹka ikansaraalu ati iroyin , eyi to ma kopa ribiribi ninu ipolongo atunyansipo Aarẹ Bọla Tinubu. Lara awọn olokiki miran ti orukọ wọn wa ninu atojọ tuntun naa ni Minisita fun Olu Ilu ilẹ wa l'Abuja, Nyesom Wike, ati Gomina Ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke. Wike ni yoo ṣe alabojuto ipolongo aarẹ ni Ipinlẹ Rivers ati Olu Ilẹ wa l'Abuja , nigba ti Adeleke yoo ṣe alabojuto ipolongo naa ni Ipinlẹ Ọṣun. Awọn miran to wa ninu ẹka ibanisọrọ ati iroyin ni Minisita fun Ọkọ Ofurufu, Festus Keyamo; Abdulmumin Jibrin; ati Lere Ọlayinka, to jẹ oluranlọwọ fun Wike lori ọrọ iroyin. Bakan naa ni wọn tun yan Ọbafẹmi George gẹgẹ bi oluranlọwọ lori ọrọ iroyin. Igbimọ na jẹ akojọpọ aw...

Ẹ fọkanbalẹ idaniloju wa pe nnkan yoo pada bọ sipo- Oluwafẹmi Abiọdun-Oni

Image
Bi gbogbo awọn ọmọ orileede yii ti n ṣajọyọ ayẹyẹ ọdun mẹrindinlaadọrin ọdun tilẹ wa, Naijiria, ti gbominira, Oludije fun ipo aṣofin agba niluu Abuja fun ẹkun Ogun Central, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, Onimọ ẹrọ Samuel Oluwafẹmi Abiọdun-Oni, ti ni idaniloju wa pe nnkan yoo si pada bọ sipo rere laipẹ. Ninu atẹjade ti oludije ọhun fọwọ si nibi to ti n ki awọn ọmọ orileede yii, ọmọ ipinlẹ Ogun ati paapaa aarin gbungbun Ogun, iyẹn Ogun Central ku ayẹyẹ ọdun ominira naa. Bẹẹ lo kesi wọn pe ki wọn ma ṣe sọ ireti nu nitori gbogbo awọn ipenija ti wọn koju ni yoo di ohun igbagbe. Abiọdun-Oni tun ṣalaye siwaju pe loootọ ni nnkan ko fi bẹẹ rọgbọ tawọn araalu n kigbe lọtun, ti wọn ki gbe losi lori bi ọrọ  aje ṣe n dẹnukolẹ. O ni oun mọ pe nipasẹ awẹ ati adura, orileede Naijiria yoo tubọ dagbasoke, ti gbogbo idojukọ akoko yii yoo di ohun itan. Oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, tun sọ pe," Mo ki gbogbo awa ọmọ orileede yii ku ayẹyẹ ọdun kẹrindinlaadọrin ominira ta a ṣe lonii. "Mo fẹẹ ki gbogbo wa lọ ni...

Ẹ fọkanbalẹ idaniloju wa pe nnkan yoo pada bọ sipo- Oluwafẹmi Abiọdun-Oni

Bi gbogbo awọn ọmọ orileede yii ti n ṣajọyọ ayẹyẹ ọdun mẹrindinlaadọrin ọdun tilẹ wa, Naijiria, ti gbominira, Oludije fun ipo aṣofin agba niluu Abuja fun ẹkun Ogun Central, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, Onimọ ẹrọ Samuel Oluwafẹmi Abiọdun-Oni, ti ni idaniloju wa pe nnkan yoo si pada bọ sipo rere laipẹ. Ninu atẹjade ti oludije ọhun fọwọ si nibi to ti n ki awọn ọmọ orileede yii, ọmọ ipinlẹ Ogun ati paapaa aarin gbungbun Ogun, iyẹn Ogun Central ku ayẹyẹ ọdun ominira naa. Bẹẹ lo kesi wọn pe ki wọn ma ṣe sọ ireti nu nitori gbogbo awọn ipenija ti wọn koju ni yoo di ohun igbagbe. Abiọdun-Oni tun ṣalaye siwaju pe loootọ ni nnkan ko fi bẹẹ rọgbọ tawọn araalu n kigbe lọtun, ti wọn ki gbe losi lori bi ọrọ  aje ṣe n dẹnukolẹ. O ni oun mọ pe nipasẹ awẹ ati adura, orileede Naijiria yoo tubọ dagbasoke, ti gbogbo idojukọ akoko yii yoo di ohun itan. Oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, tun sọ pe," Mo ki gbogbo awa ọmọ orileede yii ku ayẹyẹ ọdun kẹrindinlaadọrin ominira ta a ṣe lonii. "Mo fẹẹ ki gbogbo wa lọ ni...

Wale Olanrewaju ‘Demarkets’ Iwe Iroyin, Says Press Centre Was Worst in Nigeria Despite His 26 Projects

Image
A former Chairman of the Ogun State Council of the Nigeria Union of Journalists (NUJ) has challenged claims attributed to Comrade Wale Olanrewaju, about the condition of the union’s secretariat before his administration, describing the remarks as inaccurate,  uncivilized and unfair to past leaders. The former chairman, Comrade Wole Shokunbi, was reacting to Olanrewaju’s address during the visit of the All Progressives Congress (APC) governorship candidate in Ogun State, Senator Solomon Olamilekan Adeola, popularly known as Yayi, to the NUJ Secretariat at Iwe Iroyin Press Centre, Abeokuta, on Friday, September 25, 2026. Adeola’s visit was part of his engagement with journalists ahead of the 2027 governorship election, during which he unveiled his proposed nine-point development agenda for Ogun State.  The former chairman, in a statement made available to journalists, alleged that Olanrewaju had portrayed the secretariat he inherited as being in a state of disrepair and lacking ...

Mi o ni fẹ kawọn eeyan mi wa ninu inira ti mo ba depo ọmọ ile igbimọ aṣofin- Azeez Babatunde, ifo keji

Image
Onarebu Sadiq Azeez Babatunde, oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin fun Ifọ keji, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC,nipinlẹ Ogun, ti sọ pe ẹgbẹ wọn ti kọja eyi ti wọn le ma foju tẹmbẹlu, nitori awọn ti ṣetan lati gba akoso nibi ibo to n bọ lọdun 2027. Gẹgẹ bo ṣe wi, bi ẹru lawọn ṣe jẹ fawọn ẹgbẹ oṣelu yooku nitori wọn ko mọ ibi ti wọn yoo gba yọ si wọn lọdun to n bọ. O ṣalaye siwaju pe imọlẹ ẹgbẹ oṣelu ọhun ti tan kalẹ nibi gbogbo nipinlẹ Ogun titi to fi de awọn igberiko, eyi to mu kawọn araalu maa ṣatilẹyin fun wọn. Oludije ọmọ ile igbimọ aṣofin naa tun ṣalaye pe ẹ o rii pe lọdun to kọja nibi ibo to waye lọdun 2023, ipo kẹta lawọn ṣe, ṣugbọn lakooko yii nibi ibo to n bọ, awọn ni yoo gbegba oroke. Lori erongba ẹ lati di ọmọ ile igbimọ aṣofin, Sadiq Babatunde sọ pe oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun atilẹyin toun ri gba lati ọdọ awọn eeyan oun ni ẹkun Ifọ Keji. O ṣalaye pe awọn eeyan ni wọn fẹ ki ayipada rere deba ijọba to wa lode yii, ti wọn si ti ṣetan lati fi kaadi idibo wọn le wọn jade. Nitori ẹ ni wọn ṣe n fi ọk...

Ko ni si alafo ibaṣepọ laarin emi atawọn eeyann ti mo fẹẹ ṣoju fun nile igbimọ aṣofin ti mo ba wọle- Ọnarebu Azeez Babatunde

Image
Ọnarebu Sadiq Azeez Babatunde, oludije fun ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun fun ẹkun  Ifọ keji, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, ti mu da gbogbo eeyan agbegbe to fẹẹ lọ ṣoju fun pe  ko ni si alafo ibaṣepọ laarin emi atawọn eeyann toun fẹẹ lọ ṣoju fun toun ba wọle ninu ibo ọdun to n bọ. O sọ pe gẹgẹ bi oludije fun ipo aṣofin, iṣẹ ti wọn ni lati ṣofin lori bi idagbasoke yoo ṣe deba agbegbe ti wọn ṣoju fun, idi niyii toun fi pinnu awọn abadofin kan ti yoo mu irọrun ba Ifọ keji, ni eyi toun mọ pe o ti n jẹ awọn eeyan oun niya latọjọ to tipẹ paapaa bi owo yoo ṣe maa wọle tawọn araalu yoo si maa ri ti wọn ṣe. O ni," Bi awọn eeyan mi ni agbegbe Ifọ Keji ba le dibo fun mi gẹgẹ bi aṣofin wọn labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, mo maa rii pe ajọṣepọ to danmọran wa laarin emi atawọn araalu lati le maa mọ bi nnkan ṣe n lọ, mi o si ni jẹ aye alafo ibaṣepọ ṣi ṣilẹ laarin wa" O fikun ọrọ ẹ pe ipo toun dije fun yii ki i ṣe nipa imọtara ẹni rara bi ko ṣe lati fi sin araalu tọkantọkan ki wọn si le jẹ anfaani mudunm...

Ẹyin ara agbegbe aarin gbungbun Ogun, Ogun Central akoko to lati fibo yin Ọmọluabi Pọnbele,Oluwafẹmi Abiọdun-Oni wọle.

Image
Bi o ti ku fẹrẹ ki eto ibo waye jakejado orileede yii tawọn oludije si ti n jade lati du awọn ipo kọọkan. Bẹẹ ni ipolongo si ti bẹrẹ yatọ sipo Gomina atawọn aṣofin ipinlẹ. Ki i ṣe tuntun mọ pe ọkan lara awọn oludije fun aṣofin agba fun ẹkun aarin gbungbun iyẹn Ogun Central ni Onimọ ẹrọ Samuel Oluwafẹmi Abiọdun Oni, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, ẹni ti Ọlọrun sọ pe akoko ti to fun un lati wa sin eeyan rẹ. Ohun to daju ni pe latigba ti ajọ eleto idibo iyẹn INEC ti fi ontẹ lu agba oṣelu naa gẹgẹ bi oludije, lawọn araalu naa ti n fi atilẹyin wọn han si, ti wọn si lawọn nigbẹkẹle ninu ẹ lati jẹ aṣoju wọn niluu Abuja. Ko le ṣe ko ma ribẹ, nitori ẹni ti wọn ba ti pe ni ọmọluabi, ko si ki wọn maa ri awọn iwa alubarika yii lara ẹ. Awọn to mọ oludije ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC yii sọ pe ki i ṣe akoko to fẹẹ gbegba oṣelu lo ṣẹṣẹ di ọmọluabi, wọn ni ọmọ ba ọla nile, to tun fawọn jẹ ninu ọla ẹ ni. Ọpọ awọn ipa pataki ti wọn lo ti ko lo ti ni ẹmi sisin awọn eeyan ẹ ṣọkan, ti ko si fọrọ wọn ṣere, aṣiwaju ati adari re...