Posts

Showing posts from October, 2026

LYMP kí Ṣẹgun Ṣówùnmí kú oríire ìyànsípò rẹ̀ sínú ìgbìmọ̀ ìpolongo ààrẹ

Image
  Ẹgbẹ awọn oniroyin ni ede abinibi, League of Yoruba Media Practitioners (LYMP), ti ki gbajumọ oloṣelu ati olori pataki nilu Ẹgba, Ọdọfin Ṣẹgun Ṣowunmi, ku oriire lori iyansipo rẹ sinu igbimọ ipolongo aarẹ ti ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) ṣe atunṣe rẹ. Ṣowunmi wa lara awọn eekan igbimọ naa to ma mojuto ẹka ikansaraalu ati iroyin , eyi to ma kopa ribiribi ninu ipolongo atunyansipo Aarẹ Bọla Tinubu. Lara awọn olokiki miran ti orukọ wọn wa ninu atojọ tuntun naa ni Minisita fun Olu Ilu ilẹ wa l'Abuja, Nyesom Wike, ati Gomina Ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke. Wike ni yoo ṣe alabojuto ipolongo aarẹ ni Ipinlẹ Rivers ati Olu Ilẹ wa l'Abuja , nigba ti Adeleke yoo ṣe alabojuto ipolongo naa ni Ipinlẹ Ọṣun. Awọn miran to wa ninu ẹka ibanisọrọ ati iroyin ni Minisita fun Ọkọ Ofurufu, Festus Keyamo; Abdulmumin Jibrin; ati Lere Ọlayinka, to jẹ oluranlọwọ fun Wike lori ọrọ iroyin. Bakan naa ni wọn tun yan Ọbafẹmi George gẹgẹ bi oluranlọwọ lori ọrọ iroyin. Igbimọ na jẹ akojọpọ aw...

Ẹ fọkanbalẹ idaniloju wa pe nnkan yoo pada bọ sipo- Oluwafẹmi Abiọdun-Oni

Image
Bi gbogbo awọn ọmọ orileede yii ti n ṣajọyọ ayẹyẹ ọdun mẹrindinlaadọrin ọdun tilẹ wa, Naijiria, ti gbominira, Oludije fun ipo aṣofin agba niluu Abuja fun ẹkun Ogun Central, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, Onimọ ẹrọ Samuel Oluwafẹmi Abiọdun-Oni, ti ni idaniloju wa pe nnkan yoo si pada bọ sipo rere laipẹ. Ninu atẹjade ti oludije ọhun fọwọ si nibi to ti n ki awọn ọmọ orileede yii, ọmọ ipinlẹ Ogun ati paapaa aarin gbungbun Ogun, iyẹn Ogun Central ku ayẹyẹ ọdun ominira naa. Bẹẹ lo kesi wọn pe ki wọn ma ṣe sọ ireti nu nitori gbogbo awọn ipenija ti wọn koju ni yoo di ohun igbagbe. Abiọdun-Oni tun ṣalaye siwaju pe loootọ ni nnkan ko fi bẹẹ rọgbọ tawọn araalu n kigbe lọtun, ti wọn ki gbe losi lori bi ọrọ  aje ṣe n dẹnukolẹ. O ni oun mọ pe nipasẹ awẹ ati adura, orileede Naijiria yoo tubọ dagbasoke, ti gbogbo idojukọ akoko yii yoo di ohun itan. Oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, tun sọ pe," Mo ki gbogbo awa ọmọ orileede yii ku ayẹyẹ ọdun kẹrindinlaadọrin ominira ta a ṣe lonii. "Mo fẹẹ ki gbogbo wa lọ ni...