Ojuse gbogbo wa ni lati gbe ede ati asa wa laruge- Oloye Segun Sowunmi
' Orileede to ba sọ ede rẹ nu ti sọ idanimọ rẹ nu atipe yoo dabii orileede ti ko ni ẹyin ọla ni', Orọ yii ni gbajumọ oloṣelu, Oloye Ṣẹgun Ṣowunmi sọ lasiko ti ẹgbẹ oniroyin lede Yoruba, 'League of Yoruba Media Practitioners', ẹka ipinlẹ Ogun ṣabẹwo si i nilẹ rẹ nilu Abẹokuta. Ṣowunmi jẹ ko di mimọ pe bawọn obi ati alagbatọ ba kuna lati jẹ kawọn ọmọ wọn maa sọ ẹdẹ Yoruba, o ṣee ṣe kawọn ọdọ iwoyi koju iṣoro lọjọ iwaju latari bi wọn ko ṣe fẹran lati maa sọ ede abinibi wọn. O ni, ọrọ naa ko yọ awon olukọ paapaa silẹ, ṣe ni ki wọn mu kikọ ati sisọ ede abinibi wa ni pataki ni yara ikẹkọọ. Eekan oloṣelu naa waa rọ gbogbo ẹka igbohunsafẹfẹ ati iwe iroyin lati maa ṣe igbelarugẹ ede ilẹ kaarọ oojiire nigba gbogbo. Sowunmi gbe oṣuba o kare fawọn ọmọ ẹgbẹ naa fun igbiyanju wọn lati ri i daju pe, ede naa ko lọ soko igbagbe. O tun lo asiko naa lati rọ aarẹ orileede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati tubọ fẹsẹ imọ ẹkọ ede Yoruba mulẹ siwaju si i lawọn i...