Posts

Showing posts from March, 2026

Barr.Ọtẹgbẹyẹ Celebrates Aniṣulowo's 75th Birthday

Image
Barrister Biyi Ọtẹgbẹyẹ, the 2023 gubernatorial candidate of the African Democratic Party, ADC has celebrated Senator Iyabọ Aniṣulowo's on her 75th birthday held on Saturday in Ilaro. Barrister Otegbeye  was present at the milestone celebration and Book launch. Ọtẹgbẹyẹ described Aniṣulowo as a great mother who supports her children and loves everyone. He said Senator Aniṣulowo has made significant contributions to Ogun State, especially Yewaland. He noted Sen.Aniṣulowo's dedication to education and her efforts to improve it in Nigeria, saying she started as a teacher. Ọtẹgbẹyẹ also recalled Sen. Aniṣulowo's 2023 gubernatorial run, saying her goal was to make Yewa governor of Ogun State, and prayed it would happen soon. He wished the celebrant  long life and good health.

Awọn kanselọ Yewa sọ pe ahesọ ni pe awọn ti fa ọmọ oye silẹ

Image
Bi ọjọ meloo kan lawọn kanselọ kan ko ara wọn jọ ti wọn pariwo sita pe awọn dide laii ṣatilẹyin fun Sẹnetọ Ọlamilekan Solomon Adeọla, tọpọ mọ si Yayi lati dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun. Ṣugbọn ọrọ ti bẹyin yọ bayii nitori bawọn kanselọ kan ṣe sọ pe awọn ko mọ nnkankan nipa ẹ ati pe apo ara wọn lawọn yẹn sọ si. Nibi ipade oniroyin tawọn kanselọ naa ṣe lonii lawọn kanselọ marundinlogoji lati Ogun West labẹ ẹgbẹ wọn to jẹ ti  Dapọ Abiọdun ni wọn ti sọ pe irọ to jinna sootọ ni pe kanselọ mọkandinlọgọta to wa ni Ogun West fọwọ si Yayi. Ninu ọrọ Ọnarebu Lateef Oseni, igbakeji adari awọn kanselọ nijọba ibile Ado- Odo- Ọta, lo ti sọ pe ko si adehun kankan laarin awọn kanselọ lati jumọ fa ẹnikan kalẹ ni Ogun West fun ipo gomina. O waa kilọ fawọn agba ẹgbẹ oṣelu lagbegbe ọhun ki wọn yẹra lati fa ẹni ti ko nimọ kikun nipa agbegbe Ogun West kalẹ. O sọ pe ẹni tawọn n fẹ lati dije gomina lẹni to mọ nipa gbongbo, to sunmọ araalu, to si tun jẹ ojulowo ọmọ ilu. Ọnarebu Oseni ...

GNI pn ounjẹ fawọn alaawẹ ni wọn ba n fadura ranṣẹ si

Image
Titi di akoko ta a wa yii lawọn araalu fi adura ranṣẹ si Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka ti wọn tun pe ni GNI, to n ṣoju agbegbe Imẹkọ- Afọn/ Ẹgbado North, nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja,lori bo ṣe pin ẹbun ounjẹ fawọn alaawẹ. Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, igba akọkọ kọ ree, ti oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ APC  maa n ṣe nnkan bayii eyi ti wọn pe ni 'Ramadan Package' Bo tilẹ jẹ pe ti akoko yii yatọ nitori bawọn musulumi ṣe n gbawẹ bẹẹ lawọn onigbagbọ ta a mọ si Krisitẹẹni naa n gba. Idi niyii ti wọn fi pn awọn ẹbun ounjẹ naa kaakiri awọn ijọba ibilẹ ati wọọdu kọọkan to wa nipinlẹ Ogun. Ko si sẹni to ri awọn ẹbun ounjẹ naa ti ko ni ṣadura fẹni to ṣagbekalẹ ẹ, nitori awọn nnkan ti wọn ko sibẹ fawọn eeyan lati fi ṣara rindin. Ọpọ awọn eeyan to jẹ anfaani ẹbun ounjẹ ninu Ramadan yii ni wọn fi idunnu wọn,ti wọn si ṣadura fun Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka, ti wọn ṣi n fadura ranṣẹ sii. Ọkan lara wọn lati Abẹokuta South, Iyaafin Mọdina Salawu, dupẹ lọwọ GNI fun iranlọwọ ounjẹ ti wọn ri gba la...

Nitori GNI: Awọn Yewa lawọn ko le ta ogun ibi wọn fun Yayi lọdun 2027

Image
Bi ibo Gomina fọdun 2027, ṣe n sunmọ le lorileede yii paapaa julọ nipinlẹ Ogun, oriṣiiriṣii awọn nnkan lo ti n jẹyọ nipa awọn to fẹẹ dije, o si jẹ pe lakooko yii awọn ọmọ Yewa ko fọrọ naa ṣere rara. Idi abajọ ni pe awọn kan sọ pe bigba tawọn ta ogun ini wọn lọrọ yoo ri tawọn ba fi le gba ki Sẹnetọ Ọlamilekan Adeọla tọpọ mọ si Yayi gẹgẹ bi oludije Gomina lati apa ọdọ wọn. Ohun tọpọ wọn ka a si ni pe bìgba tawọn to fẹẹ fi eeru gba ibukun lawọn ka si, nitori bi wọn lo ṣe sọ pe ọmọ bibi Ilaro loun, to si tipasẹ bẹẹ jẹ lọ fun ipo sẹnetọ to wa yii. Wọn ni gbobo awọn iṣẹ akanṣe to n ṣe kaakiri ipinlẹ Ogun lo ye awọn, nitori ko fi le gbe wọn mọra. Eyi ti wọn sọ pe ko ṣe ida ọgọta iru ẹ nipinlẹ Ogun to ti n kọkọ ṣoju wọn fun ọpọ ọdun sẹyin, to si tumọ si pe ko le ba a gbe awọn ọmọ Ogun mọra. Loootọ lo jẹ pe lati nnkan bii aadọta sẹyin lawọn apa Ogun West ko ti jẹ gomina ri ṣugbọn tawọn mọ pe o ti to akoko fun wọn lati ni nipasẹ Ọnarebu Gboyega Nasir Isiaka, ẹni to n ṣoju wọn nile igbimọ aṣoji-ṣ...

Wọn ni Tunde Lẹmọ di ṣẹrubawọn fawọn oludije gomina ipinlẹ Ogun yooku

Image
Ki i ṣe tuntun mọ pe Tunde Lẹmọ, ẹni to ti figba kan jẹ igbakeji ọga agba banki nilẹ wa, ti jade lati dupo fun ipo gomina ninu ibo ọdun 2027, labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹOgun. Bẹẹ ni igbesẹ si n lọ lọwọ lori bi nnkan yoo ṣe ṣẹnu ire fun oludije ti idaniloju si wa pe gbogbo awọn ọmp Ẹgba ni wọn ti gbaradi lati ṣatilẹyin fun un. Gẹgẹ bi a ṣẹ  mọ lati bi ọjọ meloo kan sẹyin ni ariwo awọn oludije kan ti n lọ laarin igboro fun ibo Gomina ti yoo waye lọdun to n bọ naa. Lara awọn oludije ọhun ti iroyin wọn ti tan kaaliri ni Ambasedọ Ṣarafa Tunji Iṣọla, Senetọ Ọlamilekan Adeọla, tọpọ mọ si Yayi, Ọnsrebu Gboyega Isiaka, Ọnarebu Abiọdun Akinlade. Nigba to ya lawọn mii naa tun fi ifẹ wọn han lati dije, lara wọn ni Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, Ọnarebu Hunye, Arabinrin Mọdele Sarafa. Ṣugbọn lojiji ni ariwo tun gba igboro pe Tunde Lẹmọ naa jade lati dupo, bo tilẹ jẹ pe ahesọ lawọn kan pe e tẹlẹ, ko to di pe ọkunrin naa waa jade fun ara rẹ. Iwadi fi ye wa pe latilẹ lawọn oloṣelu kan ti n sọ pe ti Tunde L...