Bi Oluwafẹmi Abiọdun-Oni oludije sẹnetọ fun ẹkun Ogun Central labẹ ADC dẹru jẹjẹ, wọn ko mọ ọna ti yoo gba yọ si wọn.



Bi ere ni wọn kọ n pe tẹlẹ nigba ti wọn gbọ pe gbaju gbaja onimọ ẹrọ nni, Samuel Oluwafẹmi Abiọdun-Oni, ni ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, ipinlẹ Ogun, lo lati dije fun ipo aṣofin agba fun ẹkun Ogun Central, ọpọ ko gbagbọ,  ṣugbọn nigba ti ariwo ọkunrin naa ti n lọ lọtun, to n lọ si osi, ọrọ naa si ti di ẹru jẹjẹ mọ wọn lọwọ.

Gẹgẹ bi a ṣe mọ, tẹlẹtẹlẹ ariwo APC ati PDP lawọn araalu n gbọ tẹlẹ fun ibo ti yoo waye amọ bayii okiki ẹgbẹ oṣelu ADC naa ti nnkan paapaa ni aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, ohun to si faa ni bi oludije wọn ko ṣe fọrọ ibo naa ṣere, to si n sọ pẹlu ifọkanbalẹ pe oun loun yoo jawe olubori.

Ko le ma ri bẹ, nitori ọrọ agba kan to sọ pe ọmọ akin kan ko gbọdọ ṣojo, idi niyii to fi jẹ pe gbogbo nnkan to wa lọkan Abiọdun Oni lakooko yii ni bi yoo ṣe jawe olubori.

Bi a ba si ni ka sọ tododo, oludije aṣofin agba yii to wa lati ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipnlẹ Ogun ki i ṣe ọmọde nidii oṣelu, agba ọjẹ to ti fawọn iriri to di awọn ipo mu ni.

Bẹẹ lo ṣe jẹ pe ko si ninu akọsilẹ ẹ pe o ṣe awọn aṣemaṣe kan, koda awọn to baa ṣiṣẹ sọ pe adun un ba rin ma toṣi ni Abiọdun Oni Oluwafẹmi.

Nitori ẹ lo ṣe jẹ pe gbogbo awọn to ti ba ṣiṣẹ pọ ri ni wọn sọ pe ibi ti oludije yii ba n lọọ nidii oṣelu lawọn tẹle lọ.

Ki i ṣe pe ọkunrin naa ṣadeede jade gẹgẹ bo ṣe maa n sọ, o ni iṣẹ lati sin awọn araalu ti wa lọkan oun tipẹ, ati pe Ọlọrun lo tun pa a laṣẹ foun lati jade dupo, eyi ti igbagbọ ẹ yoo mu larada lati wọlẹ.

Awọn ara agbegbe Abẹokuta South, Abẹokuta North, Ọbafẹmi Owode, Ọdẹda,Ewekoro ati Ifọ ti wọn parapọ di Ogun Central la gbọ pe wọn ti ṣetan atilẹyin lati fi ibo wọn gbe e wọlé.

Idi niyii ti wọn lo fi di ẹru jẹjẹ sawọn oludije yooku lọrun.

Comments

Popular posts from this blog

Ipo Awujalẹ gbọdọ waye nipasẹ aṣa ati ilana ilẹ Ijẹbu ki i ṣe nipa oṣelu- Ọtunba Rotimi Paṣeda

Nitori GNI: Awọn Yewa lawọn ko le ta ogun ibi wọn fun Yayi lọdun 2027

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, Abiku si ede Yoruba.