Onarebu Gbamboye tu asiiri nla nipa ilu Mushin ati oja Ladipo
Lara awọn ijọba ibilẹ to ti pẹ lorileede Naijiria nijọba ibilẹ Mushin, awọn alaga to ti jẹ tẹlẹ nibẹ si ṣe daadaa ṣugbọn ara ọtọ ni ti Ọnarebu Emmanuel Bamigboye to n ṣakoso kansu naa lọwọlọwọ, laipẹ yii ni ẹgbẹ awọn akọroyin lede Yoruba 'League of Yoruba Media Practioners' ṣabewo si i lati mọ ibiti oṣelu de duro ni Mushin ati lorileede Naijiria. Ẹ ka nnkan ti alaga ba wọn sọ.
Ẹ jẹ ka kọkọ sọrọ lori ominira ijọba ibilẹ,kin ni ero tiyin lori ẹ
Ko si alaga ibilẹ kankan tinu rẹ ko nii dun sọrọ naa, ka dupẹ lọwọ aarẹ orileede yii, Aṣiwaju Bọla Tinubu fun igbesẹ akin to gbe,aarẹ naa lo mọ idi to fi gbe igbesẹ naa nitoripe ki orileede to le tẹsiwaju; o gbọdọ bẹrẹ lati ijọba ibilẹ. Ko si oloṣelu to le di ipo kankan mu bi ko ba wa lati ijọba ibilẹ kọkan toripe wọn maa beeere pe wọọdu wo lo ti wa.
Nnkan ti aarẹ ro ni pe, bi owo ba de isalẹ lọdọ alaga gbogbo agbegbe ni idagbasoke ma deba.
Ẹ jẹ ki n fi asiko yii dupẹ lọwọ gọmina ipinlẹ Eko Babajide Sanwo-Olu, bo ṣe ma n jẹ kowo wa tete dọwọ wa iyẹn lo jẹ ki awa alaga ibilẹ naa le ṣiṣẹ akanṣe lasiko. Apẹẹrẹ rere ni iru emi yii,mo ti ṣe ojuna mọto to le laaadọrun un atawọn iṣẹ akanṣe aritọkasi miiran nitoripe owo naa n tete bọ siwa lọwọ.
Irinajo oṣelu, bawo lọkọ ṣe gbe yin sori aga ọga ijọba ibilẹ
Mo ni iriri kan nigba ti mo wa lọmọde ti mo fi pinnu lati depo ti mo wa yii, ohun to ṣẹlẹ ni pe, lọjọ kan ni awọn olukọ wa ko wa lọ sibikan layajọ awọn ọmọde,ṣeni wọn sa wa sinu oorun lọjọ yẹn. Wọn ni ẹni ta n duro ko ni pe de ṣugbọn a tun duro fun wakati mẹta mi-in iyẹn lo mu mi beere lọwọ ẹgbọn mi kan pe ta ni ẹni ti wọn sa wa soorun toriẹ, lo ba ni alaga kansu ni ko si pẹ tẹni naa de, mo rii biwọn ṣe n bu ọla fun un. Lojuẹsẹ ni mo pinnu lọjọ yẹn pe emi naa ma di alaga kansu lọjọ kan.
Bo tiẹ jẹpe, ọkan lara àwọn ọmọ ileegbimọ aṣofin Eko ni mo fẹẹ ṣe tẹlẹ ṣugbọn ipo alaga lo pada bọ si mi lọwọ. Irin ajo yẹn gun diẹ ṣugbọn ẹ jẹ ki n dupẹ lọwọ baba wa Bọla Tinubu ati adari wa ni Mushin ati Odi-Olowo,Sẹnetọ Ganiu Ọlanrewaju Solomon ti wọn fa mi lọwọ soke lagbo oṣelu.
Ọmọ lile lawọn ọmọ Mushin,bawo ni ẹ ṣe n kapaa wọn atipe ki ni aṣeyọri yin lori ọrọ aabo
Awọn ọmọ lile gan o ja mọ toripe ọwọ ọlọpaa maa tẹ ọmọ to ba wu iwa kotọọ, a n ṣiṣẹ pẹlu ajọ ọtẹlẹmuyẹ paapaa julọ nitori awọn ọmọ alapamaṣiṣẹ tiwọn ma n kan ina lu ile onile loru toripe wọn fẹ ji dukia wọn.
Mo ṣe ipade pẹlu awọn obi wọn ki wọn le ba awọn ọmọ wọn sọrọ ko ma lọ di pe awọn niwọn maa bẹrẹ sii bẹbẹ kiri bawọn ọmọ wọn ba wa ni ahamọ.
Nigba tọwọ tẹ awọn olori wọn awọn ọmọ ẹyin kari bọnu ṣugbọn Ọlọurun naa ni ka fọpẹ fun.
Awọn eeyan mọ abuda Mushin mọ ọja latara oriki wọn 'Ọmọ onimushin ajina,onimushin anọdoru', ki ni akitiyan yin lati sọ ọja Mushin di ilumọọka lagbaaye
Ilumọọka ni Ọja Ladipọ tiwọn ti n ta ẹya ara ọkọ ati Ọja Dalekọ tiwọn ti n ta irẹsi,ko si ibiti wọn kii ti wa n na ọja mejeeji, awọn eeyan n wa lati ilẹ Kutọnu,Togo ati Ghana lati wa ra ẹya ara ọkọ ni Ladipọ.
A ti n gbe awọn igbesẹ kan lati ṣe awọn nnkan igbalode sinu awọn ọja yẹn ki wọn le ba igba mu.
Ọwọ to ba dilẹ ni eṣu n bẹ lọwẹ, kin lawọn eto irolagbara yin fawọn ọdọ
Ilu tiko ba ṣiro tawọn ọdọ mọ nnkan tiwọn n ṣe ko le ni ilọsiwaju toripe
bi wọn ba ṣe n gbiyanju ati fa a soke lawọn ọdọ a ma fa walẹ toripe wọn raaye ṣugbọn tọwọ ọdọ ba di ṣe lo ma gbajumọṣẹ to si maa ronu ilọsiwaju.
A ni eto irolagbara oriṣiriṣi fawọn ọdọ. O di dandan ka tọju awọn ọjọ ọla wa toripe awọn ni Ogo Mushin.
A ṣeto ẹkọṣẹ loriṣiriṣi pẹlu ṣiṣeranwọ irinṣẹ lẹyinti wọn ba kọṣẹyege tan, eto iranlọwọ wa fawọn olokoowo bakan naa ni ẹkọ ọfẹẹ wa fun ọdọ to ba ṣe daadaa julọ ninu idanwo aṣekagba lati jẹ moriya fawọn miiran kiwọn le ṣe daadaa lẹnu ẹkọ wọn,a tun ma n sanwo ajẹmọnu fawọn ọmọ wa tiwọn wa nileewe giga gẹgẹ bi iranwọ,a n ṣe e lati jẹ ki wọn le kọju si ẹkọ wọn ni.
Igbakeji yin n kọ, kin ni ibaṣepọ to wa laarin yin
Ajọṣepọ to dan mọran wa laarin emi ati igbakeji mi, Ọnarebu Tunbọsun Aruwe koda bi mo ṣe n ba yin sọrọ bayii,o wa ni Umurah to lọ gbadura fun gbogbo wa. Igbagbọ temi ni pe ka funra wa laaye lati ọgbọn inu ti Ọlọrun wa kaye le roju.
Ko si ibi tori o le gbeeyan de, ọmọẹyin le di ọga ẹ lọla, iwa taa ba wu sira wa lo ma sọrọ funwa lọjọ iwaju. Lọdun ti wọn bura fun Sẹnetọ Ganiyu Ọlanrewaju Solomon gẹgẹ bi alaga ijọba ibilẹ Mushin, okeere nimo ti n wo
o timo n sọ ninu ọkan mi pe 'Ọkunrin yii raye wa ni tiẹ' .
Emi naa n fẹ oriire fawọn ọmọ mi bẹẹni mi o gbadura ki ẹnikẹni di wọn lọwọ tori naa emi o le di igbakeji mi lọwọ o toripe emi naa ti wa nipo yẹn ri, irẹpọ wa laaarin wa.
Pẹlu iwa lile tawọn eeyan rọ mọ ọmọ Mushin njẹ ẹ tiẹ le fọwọ sọya loke okun pe ọmọ Mushin ni mi
Ko si ibi ti mo lọ ti mi o ki n jẹ ki wọn mọ pe ọmọ Mushin ni mi. Nigba kan nimo lọ sibi eto kan niluu London, bi mo ṣe sọ pe ọmọ Mushin ni mi bayii lawọn eeyan bẹrẹ sii patẹwọ,inu wọn dun bi mo ṣe ki oriki Mushin ti mo tun sọ itan iṣẹdalẹ rẹ inu gbogbo wọn dun debi pe wọn bẹrẹ si darukọ awọn adugbo tiwọn mọ ni Mushin. Ẹ wo,ko si ibi ti mo le wa ti mi o ni jẹ kiwọn mọ pe ọmọ Mushin nimi toripe ilu to ṣe e mu yangan ni.
Ilu Mushin ni awọn oloṣelu ma n peju si nigbayẹn, awọn baba Jakande,baba Solomon atawọn eekan oloṣelu nigba yẹn. Mushin naa la ti n ṣepade lasiko ti
aarẹ orileede yii,Aṣiwaju Bọla Tinubu fẹ jẹ gomina Eko nigbayẹn. Ko si oludije dupo gomina l'Ekoo to maa ni ti Mushin bawo nitori ibo tiwọn ma ri ni
Mushin ko ṣe e foju parẹ koda awọn elere to ba fẹ lokiki Mushin ni wọn ma wa bawọn ọmọ Mushin ba ti tẹwọ gbawọn,gbogbo agbaye lo tẹwọ gbawọn niyẹn,ojulowo ọmọ Mushin ni mi o.
Awọn iṣẹ akanṣe wo lawọn araalu ma fi ranti alaga Bamigboye
Ki n kọkọ dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aṣeyọri awọn iṣẹ akanṣe to waye lasiko iṣakoso mi, lakọọkọ naa bawọn eeyan ba n rin awọn ojuna mọto ti mo ṣe,wọn o ni gbagbe mi,a ṣiṣẹ lori ojuna mọto atawọn opopona ladugbo bii aadọrun,a ṣe atunṣe ati atunkọ awọn yaara ikawe lawọn ileewe wa, eto ironilagbara loorekoore,pipese awọn irinṣẹ ayẹwo ilera sawọn ileewesan abọọde ati idanilẹkọọ fawọn eleto ilera.
Comments
Post a Comment