Igba kan wa ti mi o rowo ọsibitu iya mi san ri-Olu Itori


 

 

Olu tiluu Itori, Ọba Abdul-Fatai Akamọ, ti sọ pe lara ipenija toun koju koun to depo ọba alaye nigba ti ara mama oun ko ya, ti wọn da a duro si ọsibitu UCH, niluu Ibadan, ti ko sowo lati fi tọju ẹ.

 

O ni ounjẹ ajẹku awọn alaisan lawọn jẹ nigba naa ṣugbọn oun ti dupẹ pe gbogbo ẹ ti di itan ati pe idi niyii toun fi pinnu pe oun yoo san owo awọn alaisan to ba ku diẹ kaato, ti wọn wa ni ọsibitu.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ nibi ipade oniroyin to waye lonii, lo ti sọ pe sisanwo yii wa lara awọn eto loriṣiiriṣii lawọn ti la kalẹ fayẹyẹ ọhun ọdun kọkanlelogun, to gori itẹ awọn baba nla ẹ, eyi to ti bẹrẹ bayii niluu naa, lara awọn eto mii-in tu wọn tun ni eto ẹkọ ọfẹ, sisanwo awọn tara wọn ko da ni ọsibitu, riro awọn ọdọ lagbara atawọn nnkan mii-in.

 

Ọba Akamọ sọ pe awọn ọmọleewe poli ICT, Itori, ti wọn jẹ ogun ni wọn yoo jẹ anfaani eto ẹkọ ofẹ, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira, ẹnikọọkan, bẹẹ lo ni oun yoo sanwo ọṣibitu fawọn tara wọn ko ya ti wọn da duro ni ọsibitu jẹnẹra to wa ni Ijaye ati Sacread Heart, to wa niluu Abẹokuta.

 

O fikun ọrọ ẹ pe awọn yoo tun nawọ sawọn to wa ni ọgba atunṣe Ibara, ti wọn ko ri owo beeli wọn san. Bakan naa lo ni ile awọn ọmọ ti ko niya iyẹn Stella Obasanjo Orphanage home’’ naa ko ni gbẹyin lara awọn ibi ti wọn yoo ṣabẹwo de.

 

 

Bẹẹ lo mẹnuba ẹsun ti wọn fi kan-an lori ọrọ ilẹ, Akamọ sọ pe, ‘’ Mi o bawọn ta pilọọti ilẹ to kere, depodepo pe maa ta nla niluu Itori latigba ti mo ti jọba.Ijọba lo ni awọn ilẹ ti aawọ wa lori ẹ yii koda aafin ti mo wa yii, ilẹ ijọba ni, mo pe ẹni to ba sọ pe oun loun nilẹ ki wọn jade pẹlu ojulowo iwe ilẹ   C of O.

 

" Mo ti fawọn eeyan ni ilẹ ọgbọn eeka lọfẹẹ daadaa.Gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ si wa oore-ọfẹ, eeyan ki I ba Ọlọrun jijakadi. A ni lati ṣe fawọn eeyan pada’’.

 

Ọba Akamọ wa fi akoko naa gba awọn ọdọ lamọran lati jẹ aṣoju rere, nitori idi eyi lawọn ṣe nnkan ti yoo mu wọn niṣẹ niluu, nipaṣẹ ironilagbara ti wọn fẹẹ ṣe fun wọn.

 

O waa gboriyin fun Gomina Dapọ Abiọdun lori igbiyanju ẹ fun idagbasoke imayedẹrun to ṣe siluu Itori. O ni o ti fi apẹẹrẹ lelẹ lati sọ ẹgan dofo lori ọna Itori- Ewekoro si marosẹ Eko.

Comments

Popular posts from this blog

Ipo Awujalẹ gbọdọ waye nipasẹ aṣa ati ilana ilẹ Ijẹbu ki i ṣe nipa oṣelu- Ọtunba Rotimi Paṣeda

igbagbọ ti Gbadebo Rhodes-Vivor ni si aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba la se fi joye Ọbalẹfun- Ifa White

Aregbesola ati Rhodes Vivour lawon yoo gbajoba Eko lowo Tinubu ati egbe APC