O l'agbara oo, Ewágbó ìdí tí Gbadebo Rhodes Vivor se fi egbé òsèlú Labor Party sile làti darapó mó egbé òsèlú ADC
Ọjọ Abamẹta Satide yii ni adije dupo gomina ipinlẹ Eko ni ọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Rhodes-Vivour darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC).
Rhodes-Vivour ni oun ni amọdaju pe ẹgbẹ oṣelu ADC lo ma gbe orile-ede Naijiria de ilẹ ileri ti yoo si mu kuro ni oko aṣalẹ.
Agbegbe Alimosho ni wọn ti ṣe ayẹyẹ naa botilẹjẹpe awọn jandugu oṣelu fẹ da ayẹyẹ naa ru ti awọn ọlọpa naa si tun fẹ ṣe idiwọ, sugbọn ohun gbogbo pada lọ ni rọrun.
Rhodes-Vivour sọ di mimọ pe awọn ko ṣe ipolongo ibo, ipade lasan ni awọn nṣe ti awọn si ti fi to awọn ọlọpa leti saju ọjọ ti awọn ṣe sugbọn oun ko mọ idi ti awọn ọlọpa tun fi wa lati ni ki awọn ma ṣe eto awọn.
O ni oun yoo yọju si ọga ọlọpa ipinlẹ Eko lẹyin ayẹyẹ lati mọ idi ti awọn eyan wọn tun fi wa.
Rhodes-Vivour ni lẹyin ọpọlọpọ ijiroro pẹlu awọn eyan oun ati awọn alẹnulọrọ ti ọrọ naa kan ni oun ṣe ipinnu lati lọ si ẹgbẹ oṣelu ADC.
Alaga ẹgbẹ oṣelu ADC nipinlẹ Eko, George Ashiru ki Rhodes-Vivour ati awọn eyan rẹ kabọ si aarin awọn, oni inu awọn dun lọpọlọpọ lati gba wọn mọra.
Ashiru fi da wọn loju pe wọn ki ṣe alejo ni aarin awọn, awọn ti di ikanna, awọn yoo si pawọpọ lati gbe orile-ede Naijiria de ibi giga ni.

Comments
Post a Comment