Posts

Ẹyin ara agbegbe aarin gbungbun Ogun, Ogun Central akoko to lati fibo yin Ọmọluabi Pọnbele,Oluwafẹmi Abiọdun-Oni wọle.

Image
Bi o ti ku fẹrẹ ki eto ibo waye jakejado orileede yii tawọn oludije si ti n jade lati du awọn ipo kọọkan. Bẹẹ ni ipolongo si ti bẹrẹ yatọ sipo Gomina atawọn aṣofin ipinlẹ. Ki i ṣe tuntun mọ pe ọkan lara awọn oludije fun aṣofin agba fun ẹkun aarin gbungbun iyẹn Ogun Central ni Onimọ ẹrọ Samuel Oluwafẹmi Abiọdun Oni, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, ẹni ti Ọlọrun sọ pe akoko ti to fun un lati wa sin eeyan rẹ. Ohun to daju ni pe latigba ti ajọ eleto idibo iyẹn INEC ti fi ontẹ lu agba oṣelu naa gẹgẹ bi oludije, lawọn araalu naa ti n fi atilẹyin wọn han si, ti wọn si lawọn nigbẹkẹle ninu ẹ lati jẹ aṣoju wọn niluu Abuja. Ko le ṣe ko ma ribẹ, nitori ẹni ti wọn ba ti pe ni ọmọluabi, ko si ki wọn maa ri awọn iwa alubarika yii lara ẹ. Awọn to mọ oludije ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC yii sọ pe ki i ṣe akoko to fẹẹ gbegba oṣelu lo ṣẹṣẹ di ọmọluabi, wọn ni ọmọ ba ọla nile, to tun fawọn jẹ ninu ọla ẹ ni. Ọpọ awọn ipa pataki ti wọn lo ti ko lo ti ni ẹmi sisin awọn eeyan ẹ ṣọkan, ti ko si fọrọ wọn ṣere, aṣiwaju ati adari re...

Bi Oluwafẹmi Abiọdun-Oni oludije sẹnetọ fun ẹkun Ogun Central labẹ ADC dẹru jẹjẹ, wọn ko mọ ọna ti yoo gba yọ si wọn.

Image
Bi ere ni wọn kọ n pe tẹlẹ nigba ti wọn gbọ pe gbaju gbaja onimọ ẹrọ nni, Samuel Oluwafẹmi Abiọdun-Oni, ni ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, ipinlẹ Ogun, lo lati dije fun ipo aṣofin agba fun ẹkun Ogun Central, ọpọ ko gbagbọ,  ṣugbọn nigba ti ariwo ọkunrin naa ti n lọ lọtun, to n lọ si osi, ọrọ naa si ti di ẹru jẹjẹ mọ wọn lọwọ. Gẹgẹ bi a ṣe mọ, tẹlẹtẹlẹ ariwo APC ati PDP lawọn araalu n gbọ tẹlẹ fun ibo ti yoo waye amọ bayii okiki ẹgbẹ oṣelu ADC naa ti nnkan paapaa ni aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, ohun to si faa ni bi oludije wọn ko ṣe fọrọ ibo naa ṣere, to si n sọ pẹlu ifọkanbalẹ pe oun loun yoo jawe olubori. Ko le ma ri bẹ, nitori ọrọ agba kan to sọ pe ọmọ akin kan ko gbọdọ ṣojo, idi niyii to fi jẹ pe gbogbo nnkan to wa lọkan Abiọdun Oni lakooko yii ni bi yoo ṣe jawe olubori. Bi a ba si ni ka sọ tododo, oludije aṣofin agba yii to wa lati ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipnlẹ Ogun ki i ṣe ọmọde nidii oṣelu, agba ọjẹ to ti fawọn iriri to di awọn ipo mu ni. Bẹẹ lo ṣe jẹ pe ko si...

Ilu Odo nla ni Ibadan gbalejo lọjọ ti Oloye Okunlọla Ayọdeji Babalọla di Aarẹ Aṣipa.

Image
Iṣẹ ati iwa rere ti eeyan maa n hu lawujọ lo jẹ ki wọn kawọn olori ilu maa fi wọn joye gẹgẹ bi owe Yoruba ksn to sọ pe iwa rere ni ẹṣọ eeyan. Irufẹ nnkan bẹẹ ni wọn ro mọ Oloye Okunlọla Ayọdeji Babalọla, oludasilẹ ati alaṣẹ Jasher Spritual Production, ti wọn fi joye Aarẹ Aṣipa tilu Odo Ona nla, to wa ni Idi Ayunrẹ. Ayẹyẹ oye ọhun to waye lawọn oloye ilu atawọn eeyan pataki niluu ti peju pesẹ lati fi ọla fun agba oniṣegun ibilẹ naa. Nigba to n sọrọ lakooko ti Baalẹ ilu naa Oloye Emmanuel Bello fi joye tan, Oloye Ayọdeji dupẹ lọwọ Ọlọrun fun  ayẹyẹ jijẹ oye ọhun. O sọ pe pataki ni oye Aarẹ Aṣipa ti wọn fi oun jẹ, o si jẹ ọkan gboogi ninu oye ilu ọhun. O ṣalaye siwaju pe Aṣipa jẹ ẹni to mọ ofin ati bi eto ilu yoo ṣe maa lọ laarin ilu. Nigba to n sọ nnkan ti wọn ri mọ ọn lara niluu naa, o sọ pe, " Olorin kan kọrin pe iwa rere ni ẹṣọ ilu, iwa ati iṣẹ rere mi ni wọn wo mọ mi lara. Bẹẹ ni wọn tun wo bi mo ṣe n gbe iṣẹṣe larugẹ" O tun ṣalaye siwaju pe lara iṣẹ akọkọ to wa niwaju oun ...

Ojuse gbogbo wa ni lati gbe ede ati asa wa laruge- Oloye Segun Sowunmi

Image
 ' Orileede to ba sọ ede rẹ nu ti sọ idanimọ rẹ nu atipe yoo dabii orileede ti ko ni ẹyin ọla ni', Orọ yii ni gbajumọ oloṣelu, Oloye  Ṣẹgun Ṣowunmi sọ lasiko ti ẹgbẹ oniroyin lede Yoruba, 'League of Yoruba Media Practitioners', ẹka ipinlẹ Ogun ṣabẹwo si i nilẹ rẹ nilu Abẹokuta. Ṣowunmi jẹ ko di mimọ pe bawọn obi ati alagbatọ ba kuna lati jẹ kawọn ọmọ wọn maa sọ ẹdẹ Yoruba, o ṣee ṣe kawọn ọdọ iwoyi koju iṣoro lọjọ iwaju latari bi  wọn ko ṣe fẹran lati maa sọ ede abinibi wọn. O ni, ọrọ naa ko yọ awon olukọ paapaa silẹ, ṣe ni ki wọn mu kikọ ati sisọ ede abinibi wa ni pataki ni yara ikẹkọọ. Eekan oloṣelu naa waa rọ gbogbo ẹka igbohunsafẹfẹ ati iwe iroyin lati maa ṣe igbelarugẹ ede ilẹ kaarọ oojiire nigba gbogbo. Sowunmi  gbe oṣuba o kare fawọn ọmọ ẹgbẹ naa fun igbiyanju wọn lati ri i daju pe, ede naa ko lọ soko igbagbe. O tun lo asiko naa lati rọ aarẹ orileede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati tubọ fẹsẹ  imọ ẹkọ ede Yoruba mulẹ siwaju si i lawọn i...

Oloye Olabode George di baba egbe 'League of Yoruba Media Practitioners'

Image
     Ẹgbẹ́ awon oniroyin ede Yoruba, iyen 'League of Yoruba Media Practitioners' (LYMP) ti fi oye baba egbe naa da  agba oloselu ati akinkaju omo Yoruba, Oloye Olabode Ibiyinka George lola. Ojoruu, Wesidee to koja yii leto idanilola ohun waye. Egbe naa se eyi fun mimo riri ati atileyin ti baba fun egbe yii ati fun iran Yoruba lapapo. Ọ̀pọ̀ àwọn àlejò ló péjọ síbi idalola naa, eyi ti ko yo awon omo Oloye Bode George sile, bee lawon omo egbe 'League of Yoruba Media Practitioners' naa wa nikale lati ye baba naa si Lasiko to n gbe ami idalola naa fun Oloye Bode George, Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Olaide  Gold, so pe gbogbo egbe lo fenuko lati fi agba oloselu naa se baba egbe won nitori ipa nla ati atileyin ti ko legbe ti baba naa se fun egbe yii. Nígbà tó ń gba oyè náà, Oloye  Bode dúpẹ́ gidigidi fún ọlá tí wọ́n bu fún un yii. o sì ṣèlérí pé òun yoo lo gbogbo agbára to wa nikapa oun lati  satìlẹ́yìn  fún ẹgbẹ́ náà, ki ede Yoruba ati aṣa wa le tunbo gb...

Oluwaṣeun Raheem to ni aisan kansa fẹẹ iranlọwọ yii.

Image
Ọrọ Yoruba kan lo sọ pe ko si nnkan to to alaafia nile aye yii, nitori ni wọn maa ṣe n gbadura pe ki Ọlọrun ma fi aisan bẹ wa wo. Arabinrin kan, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, Oluwaṣeun Raheem lo ti n woju ẹyin alaaanu ọmọ orileede yii fun ti aisan jẹjẹrẹ, taa mọ si kansa lati bi ọdun meloo kan sẹyin . Iwadii fi ye wa pe lati nnkan bii ọdun meloo kan sẹyin ni aisan ọhun ti n ba Oluwaṣeun finra, nibi ọyan gan an ni kansa yii ti muu, ti ko si jẹ ko gbadun ara ẹ. Irora yii ti wa pọ lapọju to fi jẹ pe gbogbo nnkan tawọn obi ẹ ni ni wọn ti taa tan to fi jẹ pe atijẹ wọn lakooko yii inira lo n jẹ fun wọn. Ninu ọrọ ti Oluwaṣeun ba oniroyin wa sọ nileewosan to wa lo ti rọ awọn ẹlẹyinju aanu lati ran oun lọwọ, ki wọn ma jẹ ko gba ẹmi oun lojiji Too, ẹnikẹni ti iwọ nipa lati ṣe iranlọwọ fun oun naa ni ẹnikeji rẹ, ẹ le fi owo naa ranṣẹ si akaunti nọmba Oluwaṣeun Raheem, 2334077316 UBA. Ẹ ṣe pupọ. ATTENTION! Please, help save Oluwaseun Raheem's  life.  She has cancer of the breast. Age: 25 Years Olu...

Barr.Ọtẹgbẹyẹ Celebrates Aniṣulowo's 75th Birthday

Image
Barrister Biyi Ọtẹgbẹyẹ, the 2023 gubernatorial candidate of the African Democratic Party, ADC has celebrated Senator Iyabọ Aniṣulowo's on her 75th birthday held on Saturday in Ilaro. Barrister Otegbeye  was present at the milestone celebration and Book launch. Ọtẹgbẹyẹ described Aniṣulowo as a great mother who supports her children and loves everyone. He said Senator Aniṣulowo has made significant contributions to Ogun State, especially Yewaland. He noted Sen.Aniṣulowo's dedication to education and her efforts to improve it in Nigeria, saying she started as a teacher. Ọtẹgbẹyẹ also recalled Sen. Aniṣulowo's 2023 gubernatorial run, saying her goal was to make Yewa governor of Ogun State, and prayed it would happen soon. He wished the celebrant  long life and good health.