Posts

Showing posts from July, 2026

Ojuse gbogbo wa ni lati gbe ede ati asa wa laruge- Oloye Segun Sowunmi

Image
 ' Orileede to ba sọ ede rẹ nu ti sọ idanimọ rẹ nu atipe yoo dabii orileede ti ko ni ẹyin ọla ni', Orọ yii ni gbajumọ oloṣelu, Oloye  Ṣẹgun Ṣowunmi sọ lasiko ti ẹgbẹ oniroyin lede Yoruba, 'League of Yoruba Media Practitioners', ẹka ipinlẹ Ogun ṣabẹwo si i nilẹ rẹ nilu Abẹokuta. Ṣowunmi jẹ ko di mimọ pe bawọn obi ati alagbatọ ba kuna lati jẹ kawọn ọmọ wọn maa sọ ẹdẹ Yoruba, o ṣee ṣe kawọn ọdọ iwoyi koju iṣoro lọjọ iwaju latari bi  wọn ko ṣe fẹran lati maa sọ ede abinibi wọn. O ni, ọrọ naa ko yọ awon olukọ paapaa silẹ, ṣe ni ki wọn mu kikọ ati sisọ ede abinibi wa ni pataki ni yara ikẹkọọ. Eekan oloṣelu naa waa rọ gbogbo ẹka igbohunsafẹfẹ ati iwe iroyin lati maa ṣe igbelarugẹ ede ilẹ kaarọ oojiire nigba gbogbo. Sowunmi  gbe oṣuba o kare fawọn ọmọ ẹgbẹ naa fun igbiyanju wọn lati ri i daju pe, ede naa ko lọ soko igbagbe. O tun lo asiko naa lati rọ aarẹ orileede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati tubọ fẹsẹ  imọ ẹkọ ede Yoruba mulẹ siwaju si i lawọn i...

Oloye Olabode George di baba egbe 'League of Yoruba Media Practitioners'

Image
     Ẹgbẹ́ awon oniroyin ede Yoruba, iyen 'League of Yoruba Media Practitioners' (LYMP) ti fi oye baba egbe naa da  agba oloselu ati akinkaju omo Yoruba, Oloye Olabode Ibiyinka George lola. Ojoruu, Wesidee to koja yii leto idanilola ohun waye. Egbe naa se eyi fun mimo riri ati atileyin ti baba fun egbe yii ati fun iran Yoruba lapapo. Ọ̀pọ̀ àwọn àlejò ló péjọ síbi idalola naa, eyi ti ko yo awon omo Oloye Bode George sile, bee lawon omo egbe 'League of Yoruba Media Practitioners' naa wa nikale lati ye baba naa si Lasiko to n gbe ami idalola naa fun Oloye Bode George, Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Olaide  Gold, so pe gbogbo egbe lo fenuko lati fi agba oloselu naa se baba egbe won nitori ipa nla ati atileyin ti ko legbe ti baba naa se fun egbe yii. Nígbà tó ń gba oyè náà, Oloye  Bode dúpẹ́ gidigidi fún ọlá tí wọ́n bu fún un yii. o sì ṣèlérí pé òun yoo lo gbogbo agbára to wa nikapa oun lati  satìlẹ́yìn  fún ẹgbẹ́ náà, ki ede Yoruba ati aṣa wa le tunbo gb...