Oloye Olabode George di baba egbe 'League of Yoruba Media Practitioners'


    
Ẹgbẹ́ awon oniroyin ede Yoruba, iyen 'League of Yoruba Media Practitioners' (LYMP) ti fi oye baba egbe naa da  agba oloselu ati akinkaju omo Yoruba, Oloye Olabode Ibiyinka George lola. Ojoruu, Wesidee to koja yii leto idanilola ohun waye.
Egbe naa se eyi fun mimo riri ati atileyin ti baba fun egbe yii ati fun iran Yoruba lapapo.

Ọ̀pọ̀ àwọn àlejò ló péjọ síbi idalola naa, eyi ti ko yo awon omo Oloye Bode George sile, bee lawon omo egbe 'League of Yoruba Media Practitioners' naa wa nikale lati ye baba naa si

Lasiko to n gbe ami idalola naa fun Oloye Bode George, Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Olaide 

Gold, so pe gbogbo egbe lo fenuko lati fi agba oloselu naa se baba egbe won nitori ipa nla ati atileyin ti ko legbe ti baba naa se fun egbe yii.

Nígbà tó ń gba oyè náà, Oloye  Bode dúpẹ́ gidigidi fún ọlá tí wọ́n bu fún un yii. o sì ṣèlérí pé òun yoo lo gbogbo agbára to wa nikapa oun lati  satìlẹ́yìn  fún ẹgbẹ́ náà, ki ede Yoruba ati aṣa wa le tunbo gbayi si i kari aye.

Ohun to daju saka nipe titi aye ni Oloye Bode George yoo maa ranti ohun tawon omo egbe 'League of Yoruba Media Practitioners' yii se fun un.

Comments

Popular posts from this blog

Ipo Awujalẹ gbọdọ waye nipasẹ aṣa ati ilana ilẹ Ijẹbu ki i ṣe nipa oṣelu- Ọtunba Rotimi Paṣeda

Nitori GNI: Awọn Yewa lawọn ko le ta ogun ibi wọn fun Yayi lọdun 2027

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, Abiku si ede Yoruba.