Onarebu Gbamboye tu asiiri nla nipa ilu Mushin ati oja Ladipo
Lara awọn ijọba ibilẹ to ti pẹ lorileede Naijiria nijọba ibilẹ Mushin, awọn alaga to ti jẹ tẹlẹ nibẹ si ṣe daadaa ṣugbọn ara ọtọ ni ti Ọnarebu Emmanuel Bamigboye to n ṣakoso kansu naa lọwọlọwọ, laipẹ yii ni ẹgbẹ awọn akọroyin lede Yoruba 'League of Yoruba Media Practioners' ṣabewo si i lati mọ ibiti oṣelu de duro ni Mushin ati lorileede Naijiria. Ẹ ka nnkan ti alaga ba wọn sọ. Ẹ jẹ ka kọkọ sọrọ lori ominira ijọba ibilẹ,kin ni ero tiyin lori ẹ Ko si alaga ibilẹ kankan tinu rẹ ko nii dun sọrọ naa, ka dupẹ lọwọ aarẹ orileede yii, Aṣiwaju Bọla Tinubu fun igbesẹ akin to gbe,aarẹ naa lo mọ idi to fi gbe igbesẹ naa nitoripe ki orileede to le tẹsiwaju; o gbọdọ bẹrẹ lati ijọba ibilẹ. Ko si oloṣelu to le di ipo kankan mu bi ko ba wa lati ijọba ibilẹ kọkan toripe wọn maa beeere pe wọọdu wo lo ti wa. Nnkan ti aarẹ ro ni pe, bi owo ba de isalẹ lọdọ alaga gbogbo agbegbe ni idagbasoke ma deba. Ẹ jẹ ki n fi asiko yii dupẹ lọwọ gọmina ipinlẹ Eko Babajide Sanwo-Olu, bo ṣe ma n jẹ ...