Posts

Showing posts from February, 2025

Igba kan wa ti mi o rowo ọsibitu iya mi san ri-Olu Itori

Image
    Olu tiluu Itori, Ọba Abdul-Fatai Akamọ, ti sọ pe lara ipenija toun koju koun to depo ọba alaye nigba ti ara mama oun ko ya, ti wọn da a duro si ọsibitu UCH, niluu Ibadan, ti ko sowo lati fi tọju ẹ.   O ni ounjẹ ajẹku awọn alaisan lawọn jẹ nigba naa ṣugbọn oun ti dupẹ pe gbogbo ẹ ti di itan ati pe idi niyii toun fi pinnu pe oun yoo san owo awọn alaisan to ba ku diẹ kaato, ti wọn wa ni ọsibitu.   Gẹgẹ bo ṣe sọ nibi ipade oniroyin to waye lonii, lo ti sọ pe sisanwo yii wa lara awọn eto loriṣiiriṣii lawọn ti la kalẹ fayẹyẹ ọhun ọdun kọkanlelogun, to gori itẹ awọn baba nla ẹ, eyi to ti bẹrẹ bayii niluu naa, lara awọn eto mii-in tu wọn tun ni eto ẹkọ ọfẹ, sisanwo awọn tara wọn ko da ni ọsibitu, riro awọn ọdọ lagbara atawọn nnkan mii-in.   Ọba Akamọ sọ pe awọn ọmọleewe poli ICT, Itori, ti wọn jẹ ogun ni wọn yoo jẹ anfaani eto ẹkọ ofẹ, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira, ẹnikọọkan, bẹẹ lo ni oun yoo sanwo ọṣibitu fawọn tara wọn ko ya ti wọn da duro ni ọsib...