Posts

Showing posts from September, 2023

Afojusun rere ti a ni fun iran Yoruba la se da egbe OPC Reform sile- Komureedi Dare Adesope

Image
   Àyà nini to oogun lọtọ, ka ni igboya ka si le ṣe bii ọmọ akin ki i tan lọrọ ẹni to ba ya akin.  Eyi lo fa a ti Aarẹ ẹgbẹ Odua People’s Congress Reformed, (OPC-R) lagbaaye, Kọmureedi Dare Adésopé, ṣe f’ọwọ rẹ gbaya, to ni eegun loun n fọwọ sọ o, ki i ṣe ẹran rara. O ni walahi, boun ba wa nibi ti aarẹ tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti paṣẹ fawọn ọba alaye nipinlẹ Ọyọ pe ki wọn dide ni, awọn Oriade naa ko ni i dide fun un, kinni kan ko si ni i ṣẹlẹ. Nibi ifọrọwerọ ti ẹgbẹ akọroyin ledee Yoruba, League Of Yoruba Media Practitioners (LYMP),  ṣe lori ayelujara pẹlu Aarẹ Adesope l’Ọjọruu lo ti sọrọ yii pẹlu alaye lorii idasilẹ ẹgbẹ OPC Reformed, Oloogbe Fredrick Faseun, Iba Gani Adams ati bẹẹ bẹẹ lọ: ‘’Orukọ mi ni Kọmureedi Dare Adesope, mo jẹ Aarẹ ẹgbẹ Oodua Peoples’ Congress Reformed. Emi ni Akọwe agba fun Ọmọwe Fredrick Fasehun nigba kan. Nnkan to bi OPC Reformed, ẹ ri i pe OPC Reformed la n pe e, labẹẹ Ọmọwe Fredrick Faseun lati kuro nigba yẹn, nnkan t...

AYEWO TI PARI LARA OKU MOHBAD, ESI NI A N RETI BAYII - ILEESE OLOPAA EKO

Image
Ileese Olopaa ipinle Eko ti f'idi re mule pe, l'eyin ayewo t'awon se si ara oku odomokunrin olorin takasufee nni, Ilerioluwa Aloba eni t'opo eeyan mo si Mohbad tabi Imole, esi ayewo naa l'awon n reti lati odo awon Dokita bayii. Won waa fi gbogbo eeyan l'okan bale pe, idajo ododo yoo w'aye, sugbon won ni ki gbogbo eeyan jinna si iwa to le fa iwadii awon s'eyin.

Obìnrin Onílù Àrà, Àràlọlá di gómìnà ẹgbẹ́ PMAN l’Ékòó

Image
Wọn ti yan gbajugbaja obinrin to n filu dara, Arabinrin Sẹrifatu Ọlamuyiwa ti gbogbo aye mọ si Ara gẹgẹ bi  gomina ẹgbẹ awọn olorin iyẹn PMAN, nipinlẹ Eko. Ọsẹ to kọja yii ni aarẹ ẹgbẹ naa, Pretty Okafor fọwọ si yiyan sipo obinrin ọlọpọlọ pipe yii gẹgẹ bi aṣaaju awọn olorin nipinlẹ Eko. Pẹlu ipo ti wọn yan an si yii,  Ara ni yoo maa tukọ ẹgbẹ yii nipinlẹ Eko titi digba ti wọn yoo fi dibo yan awọn oloye tuntun. A gbọ pe nitori ipa ribiribi ti ọmọ bibi ilu Ondo naa ti ko fun idagbasoke ati ilọsiwaju ariya lorileede yii ni wọn ṣe yan an sipo naa. Lasiko to n ba wa sọrọ, Ara ni inu mi dun, ayọ mi kun fun ipo ti wọn yan mi si yii, mo mọ pe igbagbọ ti ẹgbẹ ni si mi lo jẹ ki wọn yan mi sipo yii, mo si ṣetan lati lo gbogbo imọ ati iriri mi lati gbe ẹgbẹ yii ga ju bo ṣe wa lọ.

Oga awon onimoto nipinle Eko, MC Oluomo fun awon ebi Mohbad ni milionu marun-un Naira

Image
Alaga egbe awon onimoto nipinle Eko, Alaaji Musilu Akinsanya Mc Oluomo ti fi owo tiye re je milionu marun-un Naira ta awon ebi gbajumo olorin takasufee, Mohbad lore. Gege bi a se gbo, oga awon onimoto yii fun omo Mohbad iyen, Light ni milionu meta Naira, to si fun iya ati baba omodekunrin to ku naa milionu kookan Naira. Latigba tiroyin ohun ti kan awon eeyan lara ni  won ti n ka saara si Olu ilu

Kiateka’ le mi jade nile ri nitori airowo san, k’ọrọ too dayọ, oju ti ri- YEMKEM

Image
    Oriṣa oke jẹ n da bii onile yii, ki loju onile ti ri ko too kọle nla ki i ye ọpọ eeyan. B’olowo ba sọ ohun toju rẹ ri ko too dẹni aye n sa tọ, talaka mi-in yoo ni koun ṣaa ti maa r’ọbẹ jẹkọ lasan ti daa. Ọmọwe Akintunde Ishọla Ayẹni, Alaṣẹ ati Oludari ileeṣẹ YEMKEM International, ti wọn n ṣe oogun  iwosan ibilẹ, eni ti gbogbo eeyan tun mọ si Pathfinder lorilẹ-ede yii ati kaakiri agbaye, lo pe ọgọta ọdun laye,(60 years). N ni ẹgbẹ akọroyin ledee Yoruba, League Of Yoruba Media Practitioners (LYMP)  ba ni ko sọ iriri rẹ latọdun to ti n ba kinni ọhun bọ faye, nigba naa lọkunrin ọmọ wọn niluu Ọyẹ Ekiti naa bẹrẹ alaye nipa bo ṣe jiya, ati bo ṣe jẹ pe ọmọde mọkanla ko ba tọwọ oun ku lọjọ kan ṣoṣo, atawọn nnkan mi-in. Akintunde ṣalye, o ni:   ’’ Ṣe ẹ ri, ninu gbogbo nnkan laye yii, ka tiẹ kọkọ dupẹ lọwọ Eledumare ni, nitori pẹlu Oluwa, Ohun gbogbo ni ṣiṣe.  Mo dupẹ pe mo wa laye, mo wa laaye. Ki i ṣe irin -ajo to rọrun, irinajo to ni oriṣiiriṣii kot...

Omo adugbo kan lemi àti Pasuma, ife ti mo ni si Fuji lo gbe mi de Ajegunle lodo Saheed Osupa- Tope Nautical

Image
Ọkan pataki ninu awọn gbajumọ olorin fuji lorileede yii ni Alaaji Tọpẹ Nautical, ọpọ rẹkọọdu lọkunrin to dide lati Mushin naa ti gbe jade. Ni nnkan bii ọsẹ meloo kan seyin ni Tọpẹ Nautical gbe igbesẹ akin, ohun to ṣe nipe ṣe lo gba ọdọ ọga rẹ, Alaaji Saheed Oṣupa to ti kuro lati ọjọ pipẹ lọ. Ọjọ yii ni Nautical ati Olufimọ yanju gbogbo wahala to wa laarin wọn, ohun to ṣẹlẹ yii lo mu ki idunnu subu lu ayọ fun gbogbo awọn ololufẹ orin fuji.  Laipẹ yii ni ọkurin naa ṣe ifọrọwerọ pẹlu ẹgbẹ awọn oniroyin Yoruba, diẹ ninu ohun ti wọn jọ sọ ree. Ta ni Tọpẹ Nautical? Orukọ temi ni Alaaji Tọpẹ Nautical ọmọ Iya Aye, ṣẹ ẹ mọ pe bi iya eeyan ba ku, iya naa ni yoo ku, ẹ ma jẹ ki n fa a gun ju bẹẹyẹn lọ. Iya o si mọ, gbogbo awọn iya to ku, iya mi. Laipẹ ni a ri yin nile Alaaji Saheed Osupa, ki lo fa igbesẹ yii?   Bẹẹ ni mo lọ sile ọdun ni. Ṣe ẹ mọ pe ọga mi ni, lati ọjọ to ti pẹ, bẹẹ naa ni ọga mi naa ni Wasiu Alabi Pasuma. Nnkan to ṣẹlẹ ni pe ṣe ẹ ri nigba min-in bi eeyan ṣe ma...