Posts

Wọn ni Tunde Lẹmọ di ṣẹrubawọn fawọn oludije gomina ipinlẹ Ogun yooku

Image
Ki i ṣe tuntun mọ pe Tunde Lẹmọ, ẹni to ti figba kan jẹ igbakeji ọga agba banki nilẹ wa, ti jade lati dupo fun ipo gomina ninu ibo ọdun 2027, labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹOgun. Bẹẹ ni igbesẹ si n lọ lọwọ lori bi nnkan yoo ṣe ṣẹnu ire fun oludije ti idaniloju si wa pe gbogbo awọn ọmp Ẹgba ni wọn ti gbaradi lati ṣatilẹyin fun un. Gẹgẹ bi a ṣẹ  mọ lati bi ọjọ meloo kan sẹyin ni ariwo awọn oludije kan ti n lọ laarin igboro fun ibo Gomina ti yoo waye lọdun to n bọ naa. Lara awọn oludije ọhun ti iroyin wọn ti tan kaaliri ni Ambasedọ Ṣarafa Tunji Iṣọla, Senetọ Ọlamilekan Adeọla, tọpọ mọ si Yayi, Ọnsrebu Gboyega Isiaka, Ọnarebu Abiọdun Akinlade. Nigba to ya lawọn mii naa tun fi ifẹ wọn han lati dije, lara wọn ni Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, Ọnarebu Hunye, Arabinrin Mọdele Sarafa. Ṣugbọn lojiji ni ariwo tun gba igboro pe Tunde Lẹmọ naa jade lati dupo, bo tilẹ jẹ pe ahesọ lawọn kan pe e tẹlẹ, ko to di pe ọkunrin naa waa jade fun ara rẹ. Iwadi fi ye wa pe latilẹ lawọn oloṣelu kan ti n sọ pe ti Tunde L...

Mo jade lati dupo gomina lọdun 2027, fun itẹsiwaju ati idagbasoke ilu- Tunde Lẹmọ.

Image
Tunde Lẹmọ ẹni to ti figba kan jẹ igbakeji Gomina fun banki ilẹ wa iyẹn CBN ti ṣeleri pe oun yoo tubọ mu ìdàgbàsókè ba awon igberiko ati gbogbo ipinle Ogun lapapọ, iyẹn ti wọn ba foun ni tikẹẹti lati dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun fọdun 2027. Ọsẹ to kọja lo sọrọ yii lakooko tó ń kópa níbi ibo wọọdu to waye ni  Ita-Agemo, Isale-Igbein ní Abeokuta. Lẹmọ sọ pé ìpinnu oun lati di Gomina jẹ́ nítorí ìfẹ́ láti mú ìdàgbàsókè ba àwọn olugbe ipinle naa, ó fi kún un pé ìpínlẹ̀ Ogun ní agbára iṣẹ́ àgbẹ̀ tó nílò àwọn olórí mo nipa ona to ye ki oun gba ran awon eeyan lowo. Ó fi dá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú lójú pé ìjọba oun ko ni ní gbogbo ènìyàn Lara rara be ni oun ma je ki ìṣọ̀kan wa ninu ẹgbẹ debi pe opo eeyan lo ma Fe wa se ẹgbẹ oselu All Progressives Congress (APC). Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà àlàáfíà tí àwọn aṣòfin àgbà ṣe, ó ní, “Mi ò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ipò ara ẹni níbí, ṣùgbọ́n wíwà mi níbí lónìí ni láti fi hàn pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC jẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú àdánidá. Ẹ lè rí àwọn ènìyà...

Ipo Awujalẹ gbọdọ waye nipasẹ aṣa ati ilana ilẹ Ijẹbu ki i ṣe nipa oṣelu- Ọtunba Rotimi Paṣeda

Image
Agba oṣelu nni, Ọtunba Rotimi Paṣeda,ti sọ pe ọkan lara ipo ọba ti ko ṣe yẹyẹ tabi dagunla si, to nii ṣe pẹlu ibọwọ fun aṣa nilẹ Yoruba, ni Awujalẹ, nitori eyi, ko yẹ kawọn to n ṣakoso nipa oṣelu mu ẹmi itanjẹ wọn wọ. Ninu atẹjade kan to fi sita lo ti fi aidunnu ẹ han lori bawọn kan ṣe fẹẹ ma tọwọ oṣelu bọ yiyan Awujalẹ tilẹ Ijẹbu, eyi to sọ pe ko yẹ ko ri bẹ. O sọ pe bigba ti wọn  fẹẹ ba aṣa ati ilana to ti fidimulẹ nilẹ Yoruba jẹ ni.O ni lẹyin ti Awujalẹ to ti wa nibẹ tẹlẹ, Ọba Sikiru Adetọna waja, ninu oṣu keje, ọdun to kọja, nigba to lo ọdun marundinlọgọta lori oye. O ni "Lẹ́yìn naa ni ipo Awujalẹ ti ṣofo,ti ilana to tọ fun yíyan ọba tuntun sì ti bẹrẹ laaarín Ile-ọba Fusengbuwa, eyí tawọn ọmọ-ọba to yẹ lati dije ti jade fun ayẹwo fawọn afọbajẹ Ọtunba Paṣeda ni dipo ki wọn jẹ ki aṣa gbe ọna tiẹ, ẹdun ọkan lo jẹ bi ijọba ipinlẹ Ogun ṣe ti da ilana yíyan duro lẹẹmejì, nípa idi ti wọn pe ní ẹbẹ, aníyàn aabo ati ẹsun pe a ko tẹle ilana daadaa.  O ni idaduro to ṣẹṣẹ ju u lọ, ti ...

O l'agbara oo, Ewágbó ìdí tí Gbadebo Rhodes Vivor se fi egbé òsèlú Labor Party sile làti darapó mó egbé òsèlú ADC

Image
Ọjọ Abamẹta Satide yii ni adije dupo gomina ipinlẹ Eko ni ọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Rhodes-Vivour darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC).   Rhodes-Vivour ni oun ni amọdaju pe ẹgbẹ oṣelu ADC lo ma gbe orile-ede Naijiria de ilẹ ileri ti yoo si mu kuro ni oko aṣalẹ.   Agbegbe Alimosho ni wọn ti ṣe ayẹyẹ naa botilẹjẹpe awọn jandugu oṣelu fẹ da ayẹyẹ naa ru ti awọn ọlọpa naa si tun fẹ ṣe idiwọ, sugbọn ohun gbogbo pada lọ ni rọrun.   Rhodes-Vivour sọ di mimọ pe awọn ko ṣe ipolongo ibo, ipade lasan ni awọn nṣe ti awọn si ti fi to awọn ọlọpa leti saju ọjọ ti awọn ṣe sugbọn oun ko mọ idi ti awọn ọlọpa tun fi wa lati ni ki awọn ma ṣe eto awọn.   O ni oun yoo yọju si ọga ọlọpa ipinlẹ Eko lẹyin ayẹyẹ lati mọ idi ti awọn eyan wọn tun fi wa.     Rhodes-Vivour ni lẹyin ọpọlọpọ ijiroro pẹlu awọn eyan oun ati awọn alẹnulọrọ ti ọrọ naa kan ni oun ṣe ipinnu lati lọ si ẹgbẹ oṣelu ADC.   Alaga ẹgbẹ oṣelu ADC nipinlẹ Eko, George Ashiru ki ...

O l'agbara oo, Ewágbó ìdí tí Gbadebo Rhodes Vivor se fi egbé òsèlú Labor Party sile làti darapó mó egbé òsèlú ADC

Image
Ọjọ Abamẹta Satide yii ni adije dupo gomina ipinlẹ Eko ni ọdun 2023 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Rhodes-Vivour darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC).   Rhodes-Vivour ni oun ni amọdaju pe ẹgbẹ oṣelu ADC lo ma gbe orile-ede Naijiria de ilẹ ileri ti yoo si mu kuro ni oko aṣalẹ.   Agbegbe Alimosho ni wọn ti ṣe ayẹyẹ naa botilẹjẹpe awọn jandugu oṣelu fẹ da ayẹyẹ naa ru ti awọn ọlọpa naa si tun fẹ ṣe idiwọ, sugbọn ohun gbogbo pada lọ ni rọrun.   Rhodes-Vivour sọ di mimọ pe awọn ko ṣe ipolongo ibo, ipade lasan ni awọn nṣe ti awọn si ti fi to awọn ọlọpa leti saju ọjọ ti awọn ṣe sugbọn oun ko mọ idi ti awọn ọlọpa tun fi wa lati ni ki awọn ma ṣe eto awọn.   O ni oun yoo yọju si ọga ọlọpa ipinlẹ Eko lẹyin ayẹyẹ lati mọ idi ti awọn eyan wọn tun fi wa.     Rhodes-Vivour ni lẹyin ọpọlọpọ ijiroro pẹlu awọn eyan oun ati awọn alẹnulọrọ ti ọrọ naa kan ni oun ṣe ipinnu lati lọ si ẹgbẹ oṣelu ADC.   Alaga ẹgbẹ oṣelu ADC nipinlẹ Eko, George Ashiru ki ...

Omiyale to sele ni Ikorodu, ejo ijoba ni=Rhodes Vivour

Image
Ni ana, ajalu burúkú kan waye nilu Ikorodu latari  omi ọ̀gbàrá nla to ya kaakiri ile, to si ba dukia jẹ,  o tun fi ọpọlọpọ silẹ laini ibi aabo tabi ibùsùn.  Ajalu naa to yẹ ko gba   idahun pajawiri lẹsẹkẹsẹ lọwọ Ijọba Ipinle Eko, oṣenilanu osi tun jẹ ohun iyalẹnu nigba ti  kọmisọna ipinlẹ Eko fun eto ayika ati awọn orisun omi gba awọn olugbe agbegbe tọrọ naa kan lamọran pe ki wọn  kuro ni agbegbe naa. Idahun ti kọmisọna fii yii   kii ṣe ti ibanilọkan jẹ nikan, o tun ṣe afihan iru  iṣakoso ìjọba ipinlẹ Eko, iṣakoso to ni aibikita si iya ti awọn eyan doju kọ.  Eyi kii ṣe ajalu adayeba, o jẹ afihan kudiẹkudiẹ iṣejọba  labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ti n dari ipinle Eko. Ibere to wa nilẹ bayii ni pe, ní gbati kọmisọna ni ki awọn eyan fi ile wọn silẹ, ibọ ni ki wọn lọ? Ṣé wọn pese afin ọba fun wọn ni, abi agbala awọn oloye abi ọgbà awọn ọlọpa ni wọn ni ki wọn ma lọ.  Ko sibi meji ti wọn yoo lọ ju oju popona lọ, wọn yoo wa ma wọ sun kiri, ...

igbagbọ ti Gbadebo Rhodes-Vivor ni si aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba la se fi joye Ọbalẹfun- Ifa White

Image
Ọrọ tun ti foju han pe ojulowo ọmọ bibi ilẹ Yoruna ni oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, nipinlẹ Eko, Gbadebọ Rhodes-Vivour, nigba ti wọn tun fi joye nla kan to jẹ pe ẹni ti ki i ba ṣe ọmọ oduduwa ko le jẹ iru ẹ. Lọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun yii, ni lala lu ni gbọngan ootẹli Ayabot Events Centre, to wa lọna Ado-Odo, Badagry, nipinlẹ Eko, lọjọ naa ni Gbadebọ di Obalẹfun,aṣoju alaafia ijọ Oloriṣa Parapọ. Lọjọ ti Gbadebọ joye tuntun ọhun, gbọngan ibi ayẹyẹ naa kun fọnfọn nibi tawọn oloṣelu atawọn eeyan jakanjakan lawujọ to fi mọ awọn oniṣẹṣe ti peju pese lati waa ṣapọnle baba oloye tuntun naa. Ibeere tawọn kan n beere ni pe kin ni itumọ oye Obalẹfun ti Gbadebọ je ati pe iru awọn eeyan wo ni wọn fi n jẹ ẹ lawujọ. Ohun ta a gbọ pe o mu ki wọn fi agba ọjẹ nidii iṣẹ ayaworan ile jẹ Ọbalẹfun ati aṣoju alaafia ijọ Oloriṣa Parap ni igbagbọ ti wón sọ pe o ni si aṣa ati iṣẹṣe ilv Yoruba. Wọn ni oye naa ko wa fun iru wa ogiri wa bi ko ṣe fẹni to ba jẹ ojulowo ọmọ bibi ilẹ Yoruba, to...