Posts

Showing posts from March, 2026

Wọn ni Tunde Lẹmọ di ṣẹrubawọn fawọn oludije gomina ipinlẹ Ogun yooku

Image
Ki i ṣe tuntun mọ pe Tunde Lẹmọ, ẹni to ti figba kan jẹ igbakeji ọga agba banki nilẹ wa, ti jade lati dupo fun ipo gomina ninu ibo ọdun 2027, labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹOgun. Bẹẹ ni igbesẹ si n lọ lọwọ lori bi nnkan yoo ṣe ṣẹnu ire fun oludije ti idaniloju si wa pe gbogbo awọn ọmp Ẹgba ni wọn ti gbaradi lati ṣatilẹyin fun un. Gẹgẹ bi a ṣẹ  mọ lati bi ọjọ meloo kan sẹyin ni ariwo awọn oludije kan ti n lọ laarin igboro fun ibo Gomina ti yoo waye lọdun to n bọ naa. Lara awọn oludije ọhun ti iroyin wọn ti tan kaaliri ni Ambasedọ Ṣarafa Tunji Iṣọla, Senetọ Ọlamilekan Adeọla, tọpọ mọ si Yayi, Ọnsrebu Gboyega Isiaka, Ọnarebu Abiọdun Akinlade. Nigba to ya lawọn mii naa tun fi ifẹ wọn han lati dije, lara wọn ni Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, Ọnarebu Hunye, Arabinrin Mọdele Sarafa. Ṣugbọn lojiji ni ariwo tun gba igboro pe Tunde Lẹmọ naa jade lati dupo, bo tilẹ jẹ pe ahesọ lawọn kan pe e tẹlẹ, ko to di pe ọkunrin naa waa jade fun ara rẹ. Iwadi fi ye wa pe latilẹ lawọn oloṣelu kan ti n sọ pe ti Tunde L...