Mo jade lati dupo gomina lọdun 2027, fun itẹsiwaju ati idagbasoke ilu- Tunde Lẹmọ.
Tunde Lẹmọ ẹni to ti figba kan jẹ igbakeji Gomina fun banki ilẹ wa iyẹn CBN ti ṣeleri pe oun yoo tubọ mu ìdàgbàsókè ba awon igberiko ati gbogbo ipinle Ogun lapapọ, iyẹn ti wọn ba foun ni tikẹẹti lati dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun fọdun 2027. Ọsẹ to kọja lo sọrọ yii lakooko tó ń kópa níbi ibo wọọdu to waye ni Ita-Agemo, Isale-Igbein ní Abeokuta. Lẹmọ sọ pé ìpinnu oun lati di Gomina jẹ́ nítorí ìfẹ́ láti mú ìdàgbàsókè ba àwọn olugbe ipinle naa, ó fi kún un pé ìpínlẹ̀ Ogun ní agbára iṣẹ́ àgbẹ̀ tó nílò àwọn olórí mo nipa ona to ye ki oun gba ran awon eeyan lowo. Ó fi dá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú lójú pé ìjọba oun ko ni ní gbogbo ènìyàn Lara rara be ni oun ma je ki ìṣọ̀kan wa ninu ẹgbẹ debi pe opo eeyan lo ma Fe wa se ẹgbẹ oselu All Progressives Congress (APC). Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà àlàáfíà tí àwọn aṣòfin àgbà ṣe, ó ní, “Mi ò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ipò ara ẹni níbí, ṣùgbọ́n wíwà mi níbí lónìí ni láti fi hàn pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC jẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú àdánidá. Ẹ lè rí àwọn ènìyà...