Posts

Showing posts from January, 2026

Ipo Awujalẹ gbọdọ waye nipasẹ aṣa ati ilana ilẹ Ijẹbu ki i ṣe nipa oṣelu- Ọtunba Rotimi Paṣeda

Image
Agba oṣelu nni, Ọtunba Rotimi Paṣeda,ti sọ pe ọkan lara ipo ọba ti ko ṣe yẹyẹ tabi dagunla si, to nii ṣe pẹlu ibọwọ fun aṣa nilẹ Yoruba, ni Awujalẹ, nitori eyi, ko yẹ kawọn to n ṣakoso nipa oṣelu mu ẹmi itanjẹ wọn wọ. Ninu atẹjade kan to fi sita lo ti fi aidunnu ẹ han lori bawọn kan ṣe fẹẹ ma tọwọ oṣelu bọ yiyan Awujalẹ tilẹ Ijẹbu, eyi to sọ pe ko yẹ ko ri bẹ. O sọ pe bigba ti wọn  fẹẹ ba aṣa ati ilana to ti fidimulẹ nilẹ Yoruba jẹ ni.O ni lẹyin ti Awujalẹ to ti wa nibẹ tẹlẹ, Ọba Sikiru Adetọna waja, ninu oṣu keje, ọdun to kọja, nigba to lo ọdun marundinlọgọta lori oye. O ni "Lẹ́yìn naa ni ipo Awujalẹ ti ṣofo,ti ilana to tọ fun yíyan ọba tuntun sì ti bẹrẹ laaarín Ile-ọba Fusengbuwa, eyí tawọn ọmọ-ọba to yẹ lati dije ti jade fun ayẹwo fawọn afọbajẹ Ọtunba Paṣeda ni dipo ki wọn jẹ ki aṣa gbe ọna tiẹ, ẹdun ọkan lo jẹ bi ijọba ipinlẹ Ogun ṣe ti da ilana yíyan duro lẹẹmejì, nípa idi ti wọn pe ní ẹbẹ, aníyàn aabo ati ẹsun pe a ko tẹle ilana daadaa.  O ni idaduro to ṣẹṣẹ ju u lọ, ti ...