igbagbọ ti Gbadebo Rhodes-Vivor ni si aṣa ati iṣẹṣe ilẹ Yoruba la se fi joye Ọbalẹfun- Ifa White
Ọrọ tun ti foju han pe ojulowo ọmọ bibi ilẹ Yoruna ni oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, nipinlẹ Eko, Gbadebọ Rhodes-Vivour, nigba ti wọn tun fi joye nla kan to jẹ pe ẹni ti ki i ba ṣe ọmọ oduduwa ko le jẹ iru ẹ. Lọjọ kejila, oṣu kẹrin, ọdun yii, ni lala lu ni gbọngan ootẹli Ayabot Events Centre, to wa lọna Ado-Odo, Badagry, nipinlẹ Eko, lọjọ naa ni Gbadebọ di Obalẹfun,aṣoju alaafia ijọ Oloriṣa Parapọ. Lọjọ ti Gbadebọ joye tuntun ọhun, gbọngan ibi ayẹyẹ naa kun fọnfọn nibi tawọn oloṣelu atawọn eeyan jakanjakan lawujọ to fi mọ awọn oniṣẹṣe ti peju pese lati waa ṣapọnle baba oloye tuntun naa. Ibeere tawọn kan n beere ni pe kin ni itumọ oye Obalẹfun ti Gbadebọ je ati pe iru awọn eeyan wo ni wọn fi n jẹ ẹ lawujọ. Ohun ta a gbọ pe o mu ki wọn fi agba ọjẹ nidii iṣẹ ayaworan ile jẹ Ọbalẹfun ati aṣoju alaafia ijọ Oloriṣa Parap ni igbagbọ ti wón sọ pe o ni si aṣa ati iṣẹṣe ilv Yoruba. Wọn ni oye naa ko wa fun iru wa ogiri wa bi ko ṣe fẹni to ba jẹ ojulowo ọmọ bibi ilẹ Yoruba, to...