Posts

Showing posts from October, 2024

Ojiṣẹ lṣẹdalẹ ṣatupalẹ ewi Wọle Ṣoyinka, Abiku si ede Yoruba.

Image
Ọgbẹni Olubunmi Olukanni, tawọn kan tun pe ni Ojiṣẹ Iṣẹdalẹ, to fi orileede Amerika, ni California, ti tun ewi kan ti Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka kọ ni ede oyinbo to pe ni Abiku, si ede Yoruba. Gẹgẹ bo ṣe wi, o loun kọ lati fi sami ẹyẹ aadọrun ọdun ti agba ọjẹ naa lo lori ilẹ ati lati fi sapọnle ẹ. Ojiṣẹ Iṣẹdalẹ naa tun fikun ọrọ ẹ pe akanda ẹda ati awokọṣe rere ni Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka jẹ foun.  Ọkunrin ọhun to n gbe ni Califonia,to tun jẹ alukoro fun ẹgbẹ ọmọ Yoruba ati ẹgbẹ ọmọ Ijẹṣa to wa lọhun, tun fi kun ọrọ ẹ pe lara ẹkọ toun ri kọ lara baba naa ni ọgbọn atinuda, eyi to si wulo foun di onii yii. tun sọ pe bi wọn ba pe ori akọni, a fi ida laalẹ bẹẹ lọrọ agba ọjẹ yii jẹ ninu ka kọ itan tabi ewi to fa ọgbọn yọ, to si tun mu ẹwa ba aṣa ilẹ wa. Ojiṣẹ iṣẹdalẹ toun naa jẹ onkọwe, to fi n gbe aṣa ati ede Yoruba ga, lo ti fi ọgbọn atinuda ẹ ṣagbekalẹ ewi Abiku lọna ti yoo gba ye awọn to ba n ka a. Bẹẹ lo si tun lo awọn ẹwa ede bi Ọjọgbọn Ṣoyinka, ṣe gbe kalẹ ni oyinbo to kọ. Eyi ...