Posts

Showing posts from June, 2024

Irọ lasan lohun ti Fẹmi Jimoh n sọ kiri nipa MFM, ko sootọ nibẹ

Image
Ileejọsin Mountain of Fire and Miracles Ministries (MFM) ti ṣapejuwe ọrọ ti ọkan ninu awọn Pasitọ ṣọọṣi naa tẹlẹ sọ ninu fọnran kan to n ja rain-rain lori ẹrọ ayelujara, gẹgẹ bi irọ funfun balau. Ṣọọṣi ọhun sọ pe, o pẹ ti ọkunrin Pasitọ naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Fẹmi Jimoh ti maa n wu iwa laabi, ni gbogbo ijọ ti wọn ba gbe e lọ ṣe adari. Eyi lo mu ki wọn gbe e pada wa si olu ile ijọsin naa lati fi da sẹria fun, gẹgẹ bi ohun ibawi, nireti pe yoo yi iwa rẹ pada.  Ọrọ ti ọkunrin naa n sọ kiri naa to n jo kiri bi ina, ti n mu awuye-wuye dani, o si mu ki awọn araalu fi oju buruku wo ileejọsin naa.  Ṣugbọn, ninu ọrọ ti ileejọsin naa fi ranṣẹ si awọn oniroyin, lopin ọsẹ to kọja, wọn fi to wa leti pe ọkunrin yii, Jimoh, ati ojugba rẹ, tiyẹn n jẹ Caleb Ọlọruntẹlẹ, ti n gbero bi wọn ṣe maa ja ileejọsin naa lole, ki wọn si gbe owo ọrẹ ti wọn pe ni akọso lọ. Nigba ti wọn n ba awọn oniroyin sọrọ ni olu ileejọsin naa lọjọ Ẹti, Fraide, Agbẹjọro ṣọọṣi naa, Ọgbẹni Davidson Adejuwọn, sọ pe irọ...