Posts

Showing posts from May, 2024

Ibẹrẹ mi niwaju Dapọ Abiọdun, ni bo ṣẹ jẹ-Olu- Itori

Image
Bo tilẹ jẹ pe lati bi ọjọ meloo kan sẹyin ni awọn ọrọ kan ti n jẹ jade lori bi Olu tiluu Itori, Ọba Abdulfatai Akamọ, ṣe kunlẹ niwaju Gomina Dapọ Abiọdun, nibi ayẹyẹ kan to waye  Ṣugbọn ni bayii, Kabiyesi ti tan imọlẹ si ọrọ naa, o ni oloore oun toun ko le tẹju ẹ mọlẹ ni Dapọ Abiọdun, nitori oun to mu wahala ba agbegbe oun lati bi ọdun meloo sẹyin, ni Gomina naa fẹẹ yanju fawọn. Olu Itori ṣalaye siwaju pe, " Emi kọ ni mo sọ pe mo ni iroyin ayọ fun Gomina,nibi ti mo jokoo si lo ti sọ fun mi pe ki wọn pe mi, oun ni iroyin ayọ fun mi,nibi to jokoo si aye awọn gomina ni, ko si tọna fun mi lati jokoo sibẹ. "Mo si ni lati bẹrẹ mọlẹ lati gbọ nnkan to n sọ nitori ariwo waa nibẹ.Igba ti wọn si maa sọrọ, wọn lawọn niroyin ayọ fun mi pe ọna marosẹ atijọ, wọn maa bẹrẹ ẹ laarin ọsẹ mẹta si akoko yii. "Ati pe ọsibitu jẹnẹra to ti fẹẹ wo tan awọn yoo kọ, inu mi dun gan an ni ohun to ba si wu ẹlẹnu ni ko maa sọ, gbogbo eeyan lo ni anfaani lati sọ nnkan to ba wuu" "...

Awuyewuye to n waye lori alaga PDP nipinlẹ Ogun ati Adebutu yoo yanju laipẹ yii- Ṣowumi

Image
Ọtunba Ṣẹgun Ṣowumi,ọkan lara agba ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, ti muu da awọn ọmọ ẹgbẹ naa loju pe awuyewuye ti wọn lo n waye laarin alaga ẹgbẹ naa Oloye Sikirulae Ogundele ati Ọnarebu Ladi Adebutu ko nii pẹ yanju ati pe ọrọ ẹgbẹ ni. Lakooko to n ba oniroyin sọrọ lo ti ṣeleri pe laipẹ ni gbogbo ẹ yoo niyanju ati pe wọn fi gbaradi fun ibo gbogbogboo ẹgbẹ wọn ni. O sọ pe nipa wahala to n jẹyọ lori alaga ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ogun ati Ọnarebu Ladi Adebutu, oludije gomina nibi ibo to kọla, Ṣowumi sọ pe ẹgbẹ ti kọja ibi teeyan ti le sun ko maa han oorun. O sọ pe 'Ko si ọgbọn taa fẹẹ da, to ba jẹ pe awọn eeyan lo wa nibẹ,ayafi to ba jẹ awọn amunisin lo ku,wọn ki sii ṣe amunisin ẹgbẹ ni wọn, eyi ti wọn si n ṣe ko tii pọju,wọn gbaradi fun ipade gbogbogboo wọn ni" O ni lagbara Ọlọrun yoo niyanju lẹyin ipade gbogbogboo ti wọn fẹẹ ṣe ati pe ki wọn ma ṣe gbagbe pe alaga ẹgbẹ ni Sikirulae Ogundele, agba ẹgbẹ si ni Adebutu,ipo wọn ko papọ. Ṣowumi ni aṣẹ to wa lọwọ alaga ẹgbẹ si tun...