Baba nla abosi ni iwe ofin ta a n lo ni Naijiria- Oloye Bọde George
Oju to ri Eégún, to ri Orò to si tun ri Gẹ̀lẹ̀dẹ́ ti dopin iran wiwo lawọn agba wi. Eeyan to ti figba kan ṣe ṣọja to tun depo gomina nibẹ ko kere ninu aye o. Ka too tun wa sọ pe o ṣe Alaga ileeṣẹ ọlọkọ ofurufu orilẹ-ede yii, o tun depo igbakeji alaga ninu ẹgbẹ PDP lapaa Guusu, o si pada di igbakeji alaga apapọ pẹlu. Oloye Ọlabọde Ibiyinka George la n ba wi, ọmọ bibi ipinlẹ Eko ni. Ani Baba agba ninu oṣelu Naijiria to loun yoo filu yii silẹ bi Tinubu ba di aarẹ la n sọrọ ẹ. Baba naa ṣalaye lori ọrọ ọhun ati bi Naijiria ṣe n bajẹ si i lasiko yii, o sọ oju abẹ nikoo fun ikọ akọroyin ledeeYoruba, League Of Yoruba Media Practitioners to gba lalejo nile rẹ n’Ikoyi lọjọ Iṣẹgun to kọja, eyi lohun ti Oloye Bọde George sọ: Baba, ki lẹ le sọ pe o fa a bi wọn ṣe n ji awọn ọba alaye gbe lasiko yii? Oloye Bọde George: Naijiria asiko yii, a ko fẹran ara wa. Nnkan buruku meji kan n ba wa ja ta a dẹ fi n tanra wa jẹ, awọn nnkan naa ni ẹlẹyamẹya ati ẹ̀sìn. ...